Eyi ni b’ọwọ ṣe tẹ Fatai nibi ti oun atawọn ẹgbẹ ẹ ti fẹẹ fọ banki n’Irele 

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Lasiko ti afurasi adigunjale kan, Fatai Bání atawọn ẹgbẹ rẹ fẹẹ fọ awọn banki kan niluu Ode-Irele, n’ijọba ibilẹ Irele, nipinlẹ Ondo, ni wọn gba a mu.

Alakooso ẹṣọ Amọtẹkun ipinlẹ Ondo, Oloye Adetunji Adelẹyẹ, lo fidi iṣẹlẹ yii mulẹ fawọn oniroyin nigba to n ṣafihan Bani atawọn afurasi ọdaran mẹtadinlogoji mi-in ni olu ileeṣẹ wọn to wa ni Alagbaka, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹta, ọdun 2024 ta a wa yii.

O ni ilu Sapẹlẹ, nipinlẹ Delta, lawọn afurasi mejeeje ọhun ti wa, to si jẹ pe Bání gan-an lo gba wọn lalejo pẹlu bo ṣe jẹ pe ile rẹ ni wọn de si, nibẹ naa ni wọn si ti pari eto lori awọn banki mẹta ati ile itaja nla kan ti wọn fẹẹ digun ja lole niluu Ọrẹ, nijọba ibilẹ Odigbo.

Adelẹyẹ ni ọkan ninu awọn oṣiṣẹ ile-itaja ọhun ni Fatai, ẹni ọdun mẹtadinlogoji i ṣe, bẹẹ ni ki i ṣe pe ṣe ni wọn kan fẹẹ ja ileeṣẹ to ti n ṣiṣẹ yii lole nikan, oun atawọn ikọ rẹ ọhun ti pari eto lori bi wọn ṣe fẹẹ ji oludasilẹ ileeṣẹ ọhun gbe lẹyin ti wọn ba ja a lole tan.

O ni iṣẹ tawọn afurasi ọhun mọ ọn ṣe ju lọ ni ki wọn digun jale, ki wọn si tun ji awọn eeyan gbe lati ri owo nla gba lọwọ awọn eeyan wọn.

O ni ohun to pada tu asiri awọn ẹni ibi ọhun ni bi Bani ṣe tun gbiyanju ati gbe ọkan ninu awọn oṣiṣẹ ile-itaja ta a n sọrọ rẹ yii mọra, ki wọn le jọ ṣiṣẹ naa.

Ẹni ọhun ta a f’orukọ bo laṣiiri lo pada tu wọn fo, oun ni wọn lo lọọ tu aṣiri Bani fawọn ọga rẹ ki wọn too lọọ fi iṣẹlẹ naa to awọn ẹṣọ Amọtẹkun leti.

Adelẹyẹ ni ṣe lawọn afurasi ọdaran ọhun mura ija lasiko tawọn n gbiyanju ati fi pampẹ ofin gbe wọn, ti mẹfa ninu wọn si raaye sa lọ pẹlu bi awọn ṣe mọ-ọn-mọ kọ lati ba wọn ja nitori ọpọ ẹmi awọn alaiṣẹ to le ba a lọ ti awọn ba ṣe bẹẹ.

O ni awọn ti kan sawọn ẹṣọ alaabo nipinlẹ Delta, ti awọn si ti n ṣiṣẹ pọ lori ọna tọwọ yoo fi tẹ awọn janduku agbebọn mẹfẹẹfa to sa lọ.

Ninu ọrọ ti iyawo Fatai, Abilekọ Alọrọ Angel, ba awọn oniroyin sọ, o ni ketekete loun n gbọ nigba ti ọkọ oun n ba awọn ọmọọṣẹ rẹ sọrọ loru, ti wọn si n jiroro lori ọna ti wọn fẹẹ fi ji oludasilẹ ile-itaja naa gbe, ki aṣiri wọn too pada tu.

Adelẹyẹ ni gbogbo awọn afurasi yooku lawọn yoo foju wọn b’ale-ẹjọ ni kete ti iwadii ba ti pari lori ọkan-o-jọkan ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Leave a Reply