Eeyan meji ku, ọpọ ṣeṣe, ninu ijanba ọkọ lọna Ogbomọṣọ si Isẹyin

Ọlawale Ajao, Ibadan

Loju-ẹsẹ leeyan meji jẹ Ọlọrun nipe ninu ijanba ọkọ kan to waye loju ọna Ogbomọṣọ siluu Isẹyin, nirọlẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkandinlogun (19), oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii.

Ijanba afẹmiṣofo ọhun l’ALAROYE gbọ pe o waye nigba ti ọkọ bọọsi elero mejidinlogun (18) kan deede gbokiti nibi to ti n gbiyanju lati ya ọkọ kan to wa niwaju ẹ silẹ, ṣugbọn to deede ya bara sinu igbo, to si gbokiti.

Loju-ẹsẹ ni meji ninu awọn ero inu ọkọ bọọsi ọhun gbẹmi-in mi, ti awọn yooku si fara pa yannayanna.

Ati oku ati pupọ ninu awọn to fara pa la gbọ pe wọn gbe lọ sileewosan ijọba ipinlẹ Ọyọ to wa niluu Ogbomọṣọ.

Awakọ bọọsi ọhun, ti wọn pe ni Alhaji Lukman Omipọlẹkọ Ọlọpẹ, naa wa lara awọn to kagbako ifarapa nla ninu iṣẹlẹ naa, ẹsẹ-kan-aye-ẹsẹ-kan-ọrun lo si wa titi ta a fi pari akojọ iroyin yii.

Gẹgẹ bi Ọgbẹni Joshua Adekanye, ti i ṣe ọga agba ajọ ẹṣọ alaabo oju popo, iyẹn Federal Road Safety Commission (FRSC), ipinlẹ Ọyọ, ṣe fidi ẹ mulẹ, o ni nitosi abule ti wọn n pe ni Ahoro Dàda, loju ọna Isẹyin siluu Ogbomọṣọ niṣẹlẹ naa ti waye.

O fi kun un pe awọn oṣiṣẹ FRSC pẹlu Amọtẹkun ipinlẹ naa ni wọn gbe awọn to fara pa ninu ijanba ọhun lọ sileewosan fun itọju.

 

Leave a Reply