O ṣẹlẹ, Portable hu oku iya ẹ, eyi lohun to fi i ṣe

Monisọla Saka

Gbajumọ olorin taka-sufee ilẹ wa tawọn ọdọ fẹran nni, Habeeb Okikiọla Badmus ọmọ Ọlalọmi, tawọn eeyan mọ si Portable Zaazu Zeh, ti sọrọ lori iku mama ẹ, ati idi to fi hu oku atọdunmọdun naa kuro nibi ti wọn sin in si tẹlẹ.

Ọmọkunrin naa ṣalaye ọrọ yii lasiko ti obinrin oyinbo kan, Brooke Bailey, n fọrọ wa a lẹnu wo. O ni ọmọ ọdun mẹtala loun nigba ti mama oun jade laye.

Ati pe nitori gbigba adura loun ṣe lọọ hu oku iya naa, toun ba a, ti ko ti i jẹra kuro.

Nibi tuntun to hu oku mama ẹ wa, to si ti sin in si, ni ọkunrin to maa n pariwo, ‘wahala wahala wahala’ yii mu obinrin to n fọrọ wa a lẹnu wo naa lọ, bẹẹ lo fi kun un pe wọn ti ta ibi ti wọn sin mama oun si tẹlẹ yii fẹlomi-in, iyẹn naa si tun kun idi ti oun fi gbe oku mama oun kuro nibẹ lọ si aaye tuntun, ti oju oun ti le maa to o ni gbogbo igba.

O ni nnkan to jẹ ki ọrọ naa ka oun lara toun fi pinnu lati gbe igbesẹ yii kiakia ni nigba ti wọn ni k’oun lọọ ṣadura loju oori mama oun. O ni nigba naa loun ri i pe wọn ti ta ilẹ ibi ti wọn sin mama si, awọn to nibẹ ko si foun laaye lati debẹ. Nitori eyi, ati lati jẹ ki mama oun wa lakata oun, loun ṣe hu oku ẹ wa si ile olowo nla toun n kọ lọwọ ni Sango, ipinlẹ Ogun.

O ni, “Ibi yii ni mo sin mama mi si. Ọdun mẹtala ni mo wa nigba ti wọn ku. Nigba ti wọn ni ki n lọọ maa ṣadura nibi saaree wọn ni mo ri i pe wọn ti ta ilẹ yẹn. Mo lọọ hu oku yẹn ni, mo hu u ni, ko jẹra, mama mi ṣi wa bo ṣe wa, ko ṣe nnkan kan. A ṣetutu, a ṣe gbogbo ẹ. Mo ti sin in sibi yii nisinyii. Ibi yii ni mama mi wa bayii, mo waa fẹẹ waa wa kọ Zeh sibẹ”.

Oṣuba kare lawọn eeyan n gbe fun Portable to maa n pera ẹ ni bukaata ijọba apapọ yii, wọn ni bo tilẹ jẹ pe wọnranwọnran pọ fun un, sibẹ, o maa n sọrọ, to si maa n huwa ọlọgbọn nigba mi-in, eleyii ti eyi jẹ ọkan lara ẹ.

Wọn ni ọmọ yoo tọju oun naa.

Bẹẹ lawọn mi-in n ṣe yẹyẹ pe itan naa ko le dun lẹnu Portable, nitori meloo lara rẹ ni ọmọ ọdun mẹtala to loun wa nigba ti mama naa ku, wọn ni o ṣi maa wa lọmọ to n fi pata ṣere kiri adugbo ni, ati pe ju gbogbo rẹ lọ, nnkan daadaa ti ọmọ gidi maa n ṣe lo ti ṣe yẹn.

 

Leave a Reply