Iyawo Tinubu gba awọn ọmọ Naijiria nimọran: Ẹ yaa pada sidii iṣẹ agbẹ

Faith Adebọla

Lojuna ati wa ojutuu si ọwọngogo ọja ati ebi to gbode kan lorileede Naijiria bayii, Iyawo Olori orileede wa, Abilekọ Olurẹmi Tinubu, ti gba awọn ọmọ Naijiria lamọran pataki, o ni ki kaluku tete san ṣokoto rẹ giri, ki wọn pada sidii iṣẹ agbẹ, tori eyi lo le mu ki aye dẹrun, ki wọn si le kun ijọba apapọ lọwọ lori ilakaka lati mu ara tu araalu.

Rẹmi Tinubu sọrọ yii l’Ọjọruu, Wẹsidee, ogunjọ, oṣu Kẹta, ọdun yii, lasiko to n gbalejo Igbakeji ọga agba ajọ Iṣọkan Agbaye fun ilẹ Afrika, Amina Mohammed, lọfiisi rẹ, niluu Abuja.

Tinubu ni ko si abuja lọrun ọpẹ, o ni ojuutu to daju si eto ọrọ-aje to dẹnu kọlẹ ati ipọnju asiko yii ni iṣe ọgbin, eyi ti yoo pese anito ati aniṣẹku fawọn eeyan.

O ni ọpọ isapa Aarẹ orileede yii, Bọla Ahmed Tinubu, ni yoo ṣi seeso rere nigbẹyin, bi awọn araalu ba kun un lọwọ.

O ni: “Aarẹ ti ṣe awọn ipinnu rere. Awọn ipinnu wọnyi maa jẹ ka kọ orileede Naijiria tawọn eeyan yoo maa bọwọ fun. A gbọdọ jẹ oloootọ gẹgẹ bii araalu, lori bi a ṣe n lo awọn nnkan amuṣọrọ wa.

“Iṣẹ agbẹ ṣi ni ọna to ṣe koko lati laluyọ ninu ipenija to gbode lasiko yii. A gbọdọ maa pese nnkan funra wa labẹle, ki eto ọrọ aje wa le rugọgọ si i.”

Bakan naa ni Olurẹmi gba awọn eeyan nimọran pe ki wọn maa ni ero rere nipa orileede Naijiria. O ni: “Kẹẹ too ronu orileede eyikeyii mi-in, ti Naijiria ni kẹẹ kọkọ fi ṣiwaju na.”

Bakan naa lo sọrọ nipa ajọ Renewed Hope Initiative, eyi to n ṣagbatẹru rẹ, o ni ajọ naa ti ṣeranwọ lọpọlọpọ lẹka eto ọgbin, ironilagbara, eto ẹkọ, ipese ilera ati awọn nnkan amayedẹrun mi-in, o si loun ko ni i kaaarẹ ọkan lẹnu iṣẹ ọhun.

Leave a Reply