Ẹyin tẹẹ fẹẹ mọ iku to pa Mohbad, esi ayẹwo ẹ ti delẹ o

Faith Adebọla

O jọ pe suuru ati ireti ọlọjọ gbọọrọ tawọn ololufẹ gbajugbaja onkọrin hipọọpu to doloogbe lojiji nni, Ilerioluwa Ọladimeji Alọba, tawọn eeyan tun mọ si Mohbad, ti n ni lori ifẹ ọkan wọn lati mọ pato iku to pa a, ati esi ayẹwo tijọba ṣe si oku rẹ ti wọn hu lọjọsi, yoo so eeso rere pẹlu bijọba ṣe fidi ẹ mulẹ pe abajade esi ayẹwo naa ti pari, yoo si di mimọ fun araalu laarin ọsẹ mẹta si mẹrin sasiko yii.

Alakooso ẹka ileeṣẹ ijọba ti wọn ti n ṣe ayẹwo ẹjẹ ati ọfintoto iku abaadi nipinlẹ Eko, Lagos State DNA and Forensic Centre, Ọgbẹni Richard Somiari, lo sọrọ yii di mimọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ogunjọ, oṣu Kẹta, ọdun yii.

Richard sọrọ ọhun niwaju igbimọ oluṣewadii nile-ẹjọ Majisireeti to fikalẹ siluu Ikorodu, nibi ti igbẹjọ ti n waye lori iku Mohbad.

Ọkunrin naa ni: “A nireti pe esi ayẹwo oku Oloogbe yoo tẹ wa lọwọ laarin ọsẹ mẹta si mẹrin sigba ta a wa yii, eyi yoo si le mu ka tubọ fidi ohun to ṣokunfa iku rẹ mulẹ.

“Gbogbo ibi to ṣee ṣe ki iku rẹ ti wa la ti ṣewadii ẹ, a fẹẹ mọ boya majele ni wọn fun oloogbe jẹ, tori ko si pato ohun to fa iku ojiji naa ta a ti i mọ.

“Lọdọ wa, a nibi ta a maa n tọju awọn ẹri ati esi ayẹwo si, ibẹ si laabo daadaa. O lawọn ọna ta a n gba tọpasẹ ayẹwo ati ẹri ta a ba fi ṣọwọ siluu oyinbo lati ri i pe wọn ṣi peye sibẹ”, gẹgẹ bọkunrin naa ṣe wi.

Bakan naa ni ọkan ninu awọn ajafẹtọọ ọmọniyan to n ṣoju ajọ aladaani African Women Lawyers Association, tun gba awọn mọlẹbi Mohbad lamọran pe dipo ti wọn fi n ṣe fa-n-fa lori ẹrọ ayelujara, ti wọn n takoto ọrọ si ara wọn, o lohun to daa fun koowa wọn ni lati lọ sile-ẹjọ, ki onikaluku fi aidunnu ati ẹdun ọkan rẹ han lọna to yẹ.

Lẹyin igbẹjọ naa, Onidaajọ T. A. Shotobi, sun igbẹjọ si ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2024, o si rọ gbogbo awọn tọrọ kan lati peju pesẹ si kootu lọjọ naa.

Ẹ oo ranti pe ọjọ kejila, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2023 ni Mohbad ku lojiji si agbegbe Lẹkki, l’Erekuṣu Eko to n gbe. Iku ojiji ọhun fa ọpọlọpọ awuyewuye nigboro ati lori ẹrọ ayelujara, pẹlu bawọn eeyan ṣe pe fun iwadii ijinlẹ lati mọ ohun to da ẹmi irawọ onkọrin taka-sufee to ṣẹṣẹ n goke agba bọ ọhun legbodo.
Latigba naa ni igbẹjọ ati iwadii ti n lọ lati mọ ohun to pa Mohbad.

Leave a Reply