Wọn ti ko ‘ma-mu-gaari’ sọwọ ṣọja to gun DPO lọbẹ ni Kwara

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Akolo ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, ni afurasi ṣọja kan, Suleiman Sidiq, wa bayii. Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe ṣe lo lọọ ṣe akọlu ṣawọn ọlọpaa niluu Sìnàwu, lagbegbe Iléṣà-Bàrùbá, nipinlẹ Kwara, to si gun gun DPO kan lọbẹ.

ALAROYE gbọ pe ọrọ ilẹ ti wọn n ja si ni wọn fẹẹ yanju lagọọ ọlọpaa, ṣugbọn ṣe ni Suleiman Sadiq, to mu ẹsun lọ si agọ ọlọpaa ọhun ko ṣe suuru mọ, o lo ba kọ lu ASP Okeowo Joel, nigba ti DSP Marufu Keji, naa tun da si ọrọ ọhun ni Sadiq fa ọbẹ yọ ninu akọ, o gun un lọbẹ lori, o si gun DPO lọbẹ lọwọ alaafia, nitori pe gbogbo igbiyanju wọn lati pẹtu si i lọkan lo ja si pabo.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro ọlọpaa ni Kwara, Ejirẹ Adeyẹmi Adetoun, fi sita lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, lo ti ni awọn yoo ri i daju pe idajọ ododo lawọn ṣe lori ọrọ naa.

O ni, “Laaaro kutukutu ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ogunjọ, oṣu Kẹta yii, ni ọkunrin ọmọ ologun ilẹ wa, Suleiman Sadiq, to n ṣiṣẹ ni Sector3 Garrison, Mongunu, Maiduguri, fẹsẹ ara ẹ rin wa sileeṣẹ ọlọpaa niluu Sìnàwu, to si mu ẹsun ọrọ ija ilẹ kan wa. Wọn ni ki awọn tọrọ kan pada wa lọjọ keji ti i ṣe ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹta yii, ki wọn le ba wọn yanju ẹ. Ṣugbọn ṣe ni Sadiq, tutọ soke to si foju gba a, gbogbo igbiyanju awọn ọlọpaa lati pẹtu si i lọkan lo ja si pabo. O fa ọbẹ yọ, o gun DSP Marufu Keji lori, o si tun gun DPO lọbẹ lọwọ bakan naa, lo ba fere ge e ki ọwọ too pada tẹ ẹ. A si ti fi panpẹ ofin gbe e ni ibamu pẹlu ofin”.

O tẹsiwaju pe ẹka ileeṣẹ ọlọpaa ti wọn ti n ṣewadii iwa ọdaran to wa niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, ni wọn taari Sadiq lọ lẹyin ti wọn ko galagala (ankọọfu), si i lọwọ, ti wọn si gba bata lẹsẹ rẹ, ti iwadii si n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ naa.

Adetoun, ni awọn agbofinro to gun lọbẹ ti n gba itọju nileewosan bayii.

 

Leave a Reply