O ṣẹlẹ, tọọgi kọ lu awọn afọbajẹ l’Ararọmi-Ekiti  

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti 

Ọrọ a o jọba, a ko jọba ti mu wahala nla dani, to si ti di ohun tawọn tọọgi n lu awọn afọbajẹ lalubami niluu Ararọmi-Ekiti, nijọba Ibilẹ Ijero.

O ṣe diẹ ti rogbodiyan ati fa-a-ka-ja-a ti n waye laarin awọn afọbajẹ ati awọn idile to n jọba niluu naa.

Meji lara awọn afọbajẹ ilu naa, Oloye Olu Atoyebi, to jẹ Eisa ilu naa ati Oloye Samuel Atẹwọgboye, to jẹ Ojumu ti ilu Ararọmi, ṣalaye fun ALAROYE pe ni nnkan bii aago kan oru ni awọn janduku naa wọ iluọhun wa, ti wọn si ṣakọlu sile awọn afọbajẹ naa. Wọn sọ pe ọkan ninu awọn ọmọọba to n idije fun ipo naa lo ran awọn janduku yii lati waa ṣe akọlu si awọn afọbajẹ ọhun.

Awọn afọbajẹ yii ni ni kete tawọn janduku yii wọ ilu naa ni wọn bẹrẹ si i ju igi, okuta ati awọn ohun ija oloro mi-in si ori orule awọn, eyi to da jinni-jinni ati ipaya silẹ laarin ilu.

Wọn ni ọkan lara awọn ọmọọba to n idije fun ipo yii lo ti kọkọ fi ọlọpaa ko awọn ọdọ ilu naa nigba kan, to si fiya gidi jẹ wọn nitori pe wọn ko gbe lẹyin rẹ lati jẹ ọba ilu naa.

Lara ẹsun miiran ti wọn tun fi kan ọmọọba to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu kan ti wọn ko feẹ darukọ nipinlẹ Ekiti, ni pe o ti pari gbogbo eto pẹlu ijọba lati yan ajẹ́lẹ́ (Warrant Chief) ti yoo fi i jẹ gẹgẹ bii oba ni ilu naa, bo tilẹ jẹ pe ọrọ ọba jijẹ niluu naa ti wa nile-ẹjọ.

Ohun ti wọn lo n bi ọmọọba yii ninu ni bi awọn ọmọ oye yooku ṣe fi dandan le e pe afi ti wọn ba da Ifa ni gbangba, lati mọ ẹni ti ipo ọba naa tọ si laarin awọn ọmọọba bii mẹrin ti wọn n du ipo naa.

Awọn afọbajẹ wọnyi ati awọn araalu wa n rawọ ẹbẹ si ijọba ipinlẹ Ekiti, pe ki wọn ma ṣe gbe lẹyin ẹnikẹni ninu awọn ọmọọba to n dije yii.

Bakan naa ni wọn tun ran ijọba ipinlẹ Ekiti leti idi pataki to ṣe yẹ ki wọn ni suuru, ki wọn si tọ  ilana iṣẹmbaye ti wọn fi n yan ọba ilu naa latigba ti wọn ti tẹ ilu naa do. Wọn tun sọ fun ijọba pe ko duro titi di igba ti ile-ẹjọ yoo fi yanju ẹjọ to wa niwaju wọn nipa ọrọ oye ọhun.

Leave a Reply