Iru ki waa leleyii! Baale ile yii lu iyawo rẹ pa nitori ọrọ ti ko to nnkan

Adewale Adeoye

Ko jọ pe Ọgbẹni Emmanuel Okpara yoo bọ ninu wahala to ko ara rẹ si bayii pẹlu bo ṣe lu iyawo to gbe sile, Oloogbe Patience Johnson, ẹni ogoji ọdun, titi ti ẹmi fi pada bọ lara obinrin naa, nitori ọrọ ti ko to nnkan. Awọn ọlọpaa agbegbe Ẹlẹrẹ, ni Agege, nipinlẹ Eko, ti nawọ gan baale ile naa, o si ti n ṣalaye ohun to ri to fi fibinu ran iya awọn ọmọ rẹ lọ sọrun apapandodo.

ALAROYE gbọ pe ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, ni ija kekere kan ti ẹnikẹni ko mọ ohun to fa a waye laarin awọn tọkọ-taya ọhun nile ti wọn n gbe lagbegbe Agege, kawọn araale wọn si too mọ ohun to n ṣẹlẹ, Ọgbẹni Emmanuel ti lu iyawo rẹ bajẹ debii pe ṣe lo n pọ ẹjẹ lẹnu.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, S.P Benjamin Hundeyin to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun yii, sọ pe awọn araale ni wọn pe ọkan lara awọn ọmọ ti oloogbe naa bi sita lori foonu pe ko waa wo ara ti ọkọ iya rẹ fi i da ninu ile wọn. Ọmọ ọhun torukọ rẹ n jẹ Destiny lo sare lọ sile ti iya rẹ n gbe, o ba a nile lẹsẹ-kan-aye, ẹsẹ-kan-ọrun. Ko si fakoko ṣofo to fi gbe e lọ sileewosan alaadani kan to wa lagbegbe naa fun itọju. Ibi tawọn dokita ti n gbiyanju lati du ẹmi obinrin naa lo ti jupa jusẹ silẹ, to jade laye ni nnkan bii aago mẹfa aarọ kutukutu ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun yii.

Kia ni wọn ti lọọ fi iṣẹ̀ẹ naa to awọn agbofinro leti, awọn ni wọn si lọọ fọwọ ofin mu Emmanuel to lu iyawo rẹ pa nibi to sa pamọ si.

Wọn ti gbe oku oloogbe naa lọ si mọṣuari kan to wa ni ‘Mainland General Hospital’, fun ayẹwo ohun to pa a.

Awọn ọlọpaa ti ṣeleri pe lẹyin ti esi ayẹwo tawọn ṣe ba jade lawọn maa too foju Emmanuel bale-ejọ.

 

Leave a Reply