Niṣe lawọn eleyii maa ṣe bii ero ọkọ, foonu awọn ero ni wọn maa n dọgbọn ja gba

Adewale Adeoye

Awọn agba bọ wọn ni ọjọ gbogbo ni tole, ọjọ kan ni t’olohun, bẹẹ gẹlẹ lọrọ ri fawọn ole ẹlẹni meji kan, Collins Akpinoba, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, ati Ọgbẹni David Paulson, ẹni ọdun mejidinlogoji, to jẹ pe foonu igbalode ti awọn ero to wa ninu Kẹkẹ Marwa ba mu lọwọ ni wọn maa n ja gba lọwọ wọn. Ṣugbọn meji ninu wọn ti ko sakolo ọlọpaa, awọn agbofinro agbegbe Asaba, nijọba ibilẹ Asaba, nipinlẹ Delta, tẹ  meji ninu wọn.

ALAROYE gbọ pe foonu ọkunrin kan torukọ rẹ n jẹ Ezeugwu Akanso, ni awọn oniṣẹ ibi naa ji lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, lagbegbeAsaba, ni nnkan bii aago mẹfa kọja iṣẹju mẹẹẹdogun.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, S.P Bright Edafe, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun yii, sọ pe gbara ti Ọgbẹni Akanso ṣakiyesi pe foonu ọwọ oun ti poora lo ti figbe bọnu, tawọn eeyan to wa nibi ti iṣẹlẹ ọhun ti waye si ti n fimu finlẹ kaakiri. Nitori bi awọn oniṣẹ ibi naa ṣe tẹsẹ mọrin ti wọn n sa lọ lo mu ki awọn eeyan kan bẹrẹ si i le wọn lọ. Ọwọ ba ọkan lara wọn, loju-ẹsẹ lo si ti jẹwọ pe loootọ, oun loun yọ foonu ọhun, ṣugbọn oun ti fun ẹni keji oun. Wọn ri ẹnikeji rẹ naa mu, nigba ti wọn si yẹ ara rẹ wo, wọn ba foonu ọhun lọwọ rẹ, ni wọn ba fa wọn le ọlọpaa lọwọ.

Alukoro ni inu Kẹkẹ Marwa lawọn oniṣẹ ibi naa maa n lo lati ja awọn araalu lole foonu olowo iyebiye wọn, wọn aa ṣe bii ẹni pe awọn jẹ ero, ṣugbọn foonu ati dukia ni wọn fẹẹ ji gbe sa lọ.

O ni awọn maa too foju awọn ọdaran ọhun bale-ẹjọ

Leave a Reply