N’llọrin, Haruna ti n lọ si ọgba ẹwọn ba a ṣe kọwe rẹ, jibiti to lu lo n gbe e lọ

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ile-ẹjọ giga kan niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, ti sọ ọkunrin kan to maa n ya foto, Usman Haruna, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn, sẹwọn oṣu mẹfa lori ẹsun lilu jibiti ori ayelujara.

Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ati ṣiṣe owo ilu kumọkumọ nilẹ yii (EFCC), lo wọ Usman Haruna to n ṣiṣẹ fotọ yiya lọ siwaju ile-ẹjọ lori ẹsun pe o n lo ayelujara lati fi lu ọpọ ti ko mọwọ mẹsẹ ni jibiti pẹlu oniruuru ẹri niwaju ile-ẹjọ, leyii to ta ko ofin ilẹ wa. Wọn ni ṣe ni o lo ọgbọn alumọkọrọyi lati fi lu jibiti ẹgbẹrun mẹẹẹdogun Naira niluu Màlété, nijọba ibilẹ Móòrò, ninu oṣu Keji, ọdun 2024 yii.

Charles Oni, lo ṣoju EFCC ni kootu, to si ko gbogbo awọn ẹri siwaju ile-ẹjọ.

Usman gba pe oun jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an, o ni lati ọdun 2016, ni oun ti bẹrẹ iṣẹ Yahoo-Yahoo ṣiṣe.

Nigba ti Onidaajọ Muhamud Abdulgafar n gbe idajọ rẹ kalẹ, o ni lẹyin ẹkunrẹrẹ iwadii ati awọn ẹri to daju, Usman jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.; O waa paṣẹ pe ko lọ sẹwọn oṣu mẹfa pẹlu iṣẹ aṣekara, tabi ko san owo itanran ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un Naira (100,000). Ki gbogbo dukia ati owo ti wọn ba ninu asunwọn bamki rẹ di tijọba apapọ.

Leave a Reply