Oluwoo ṣedaro Imaamu agba ilu Iwo to doloogbe

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Wọn ti kede iku Imaamu Agba ilu Iwo,  Sheik AbdulFatahi Olododo, ẹni to jade laye lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun yii.

Ninu ọrọ ibanikẹdun rẹ, Oluwoo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi, ṣapejuwe iku baba naa gẹgẹ bii adanu nla fun awọn Musulumi ilu Iwo ati ti ilẹ Yoruba lapapọ.

O ba gbogbo awọn eeyan agboole Fojugbagi, niluu Iwo, awọn olujọsin ni Oluwo Central Mosque, ati gbogbo Musulumi ilẹ Yoruba kẹdun Olododo to rewalẹ asa.

Ọba Akanbi sọ pe Musulumi tootọ, to di opo ẹsin mu ninu itan ilẹ Iwo ni ọkunrin naa.

O ni ẹkọ diduro lori otitọ ti oun kọ ninu ẹsin Islam lo jẹ ki Olododo di Imaamu Agba ilu Iwo, o ni oun ko si ni i yẹsẹ ninu eleyii lori iṣakoso mọṣalaaṣi naa.

Oluwoo fi kun ọrọ rẹ nipasẹ Akọwe iroyin rẹ, Alli Ibraheem, pe ilu Iwo jẹ ilu to ni itan to dangajia ninu Islam, Baba Imaamu ọhun ko si gbọjẹgẹ ninu ilana ẹsin naa. O ni ọpọlọpọ awọn eeyan ni wọn gbe igbesẹ ta ko baba naa lasiko to fẹẹ di Imaamu Agba, ṣugbọn oun duro lori otitọ.

Ọba Akanbi gbadura pe ki Ọlọrun fi ori gbogbo aiṣedeede baba naa jin in, ko si tẹ ẹ si afẹfẹ rere.

Leave a Reply