Awọn ọlọpaa le adigunjale mẹrin bii ehoro ni Sango, ọwọ ba meji ninu wọn

Faith Adebọla

Ọwọ palaba meji ninu ikọ adigunjale ẹlẹni mẹrin kan ti segi nipinlẹ Ogun, niṣe lawọn afurasi naa n fi ọkọ wọn gbero lati ja awọn ero ọkọ ọhun lole, eyi ti wọn fi n daṣa ‘one chance’, amọ awọn ọlọpaa kẹẹfin wọn, wọn si gba fi ya wọn, titi tọwọ fi ba meji ninu wọn.

Orukọ awọn mejeeji tọwọ ba, ni Aliu Oyetọla, ẹni ọdun marundinlogoji, ati Ṣeyi Afọlabi, ẹni ogoji ọdun.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Ọmọlọla Odutọla, fi ṣọwọ s’ALAROYE lori ikanni wasaapu rẹ, o ni lọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, ni ẹnikan to ko sakolo awọn oniṣẹẹbi ọhun sunkun wa si teṣan ọlọpaa ẹka ti Sango-Ọta, nipinlẹ Ogun. Onitọhun ṣalaye pe niṣe loun wọ ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Corolla ti wọn fi n ṣe takisi, ọja Ijakọ, nijọba ibilẹ Ifọ, loun ti wọkọ ọhun, ilu Itori, nijọba ibilẹ Ewekoro, loun si n lọ. Afi bawọn ṣe de idaji ọna, ti ilu yipada, orin eegun dorin oro, niṣe lawọn toun ro pe ero ọkọ bii toun ni wọn nigba t’oun wọle di adigunjale, ni wọn ba yọ nnkan ija soun, wọn si fipa mu oun lati ko gbogbo dukia to wa lọwọ oun fun wọn.

O ni wọn gba foonu igbalode ‘smartphone’ oun ti iye rẹ jẹ ẹgbẹrun lọna marundinlaaadọrun naira (N85,000), wọn fa ẹgbẹrun mẹtalelọgọfa Naira (N123,000), owo to wa ninu akaunti toun fi n ṣe okoowo POS oun yọ. Bẹẹ ni owo beba, iyẹn ‘cash’ to wa ninu wọlẹẹti oun to jẹ ẹgbẹrun marundinlaaadọfa Naira (N105,000), naa lọ si i. O lẹyin ti wọn ti ja oun si okolombo tan ni wọn ba ti oun bọ silẹ lori ere, wọn si tẹna mọ ọkọ, wọn sa lọ rau.

Gbara ti DPO ẹka Sango ti gbọ siṣẹlẹ yii lo ti paṣẹ fawọn ọmọọṣẹ ẹ lati wa lojufo, ki wọn bẹrẹ si i fimu finlẹ, boya wọn aa le ri awọn oniṣẹẹbi naa mu laipẹ.

Ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹjidinlọgbọn, oṣu Kẹta yii, awọn ọlọpaa n ṣiṣẹ patiroolu wọn lọ jẹẹjẹ lagbegbe Itori, amọ nitori wọn ti gbọ apejuwe iru ọkọ ayọkẹlẹ tawọn atilaawi fi n ṣiṣẹ adigunjale wọn, wọn bẹrẹ si i ṣọ awọn ọkọ, lọgan tawọn afurasi ọdaran yii si ti fura pe afaimọ ni ki i ṣe awọn lawọn ọlọpaa ti wọn n wo bakan-bakan yii fẹẹ mu, wọn ko ṣe meni ṣe meji, niṣe ni wọn bẹ jade ninu ọkọ Toyota Corolla wọn, ni wọn ba juba ehoro, wọn n sa lọ.

Awọn ọlọpaa naa gba fi ya wọn, wọn le wọn bii aja to n ṣọdẹ ẹran, ọwọ si ba awọn meji yii, Ṣeyi ati Aliu, nigbẹyin.

Nọmba ara ọkọ ayọkẹlẹ ti wọn fi n pa araalu lẹkun ọhun ni LAGOS GGE 659 FR, awọn buluu ni wọn kun un.

Ṣa, awọn afurasi mejeeji yii ti n ka boroboro lakata awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ti wọn n wadii ẹsun idigunlale ni olu-ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, to wa l’Eleweran, wọn ni wọn ti n ran awọn ọlọpaa lọwọ lojuna bọwọ ṣe maa tẹ awọn ẹmẹwa wọn ti wọn sa lọ ọhun.

Alukoro Ọdutọla ni tiwadii ba ti pari, ati awọn afurasi yii, ati ọkọ ayọkẹlẹ wọn, lawọn yoo gbe lọ si kootu.

Leave a Reply