Eyi ni ohun ti Adeleke sọ nipa Tinubu

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Gomina ipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke, ti ṣapejuwe Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, gẹgẹ bii aṣiwaju to ni afojusun rere fun ọjọ iwaju orileede Naijiria.

Ninu ọrọ ti Adeleke fi sita nipasẹ Akọwe iroyin rẹ, Mallam Rasheed Ọlawale, lati fi ki Tinubu ku oriire ayẹyẹ ọjọọbi ọdun kejilelaaadọrin to pe lori eepẹ ni gomina ti sọ pe akinkanju to nigboya lati gbe awọn igbesẹ to nira, ṣugbọn ti yoo ja si ibukun fun awọn araalu ni Tinubu.

Adeleke ṣalaye pe oniruuru eto ti Aarẹ Tinubu ti dawọ le latigba to ti de ori aleefa n ṣafihan pe ireti ṣi wa fun orileede Naijiria lati de ilẹ to n ṣan fun wara ati fun oyin.

O ni ifarajin ati aikaaarẹ ati ọgbọn inu ti Eledumare fi jinki Aarẹ lo n mu ki orileede yii bọ ninu oniruuru ipenija to ti wa tẹlẹ.

Gẹgẹ bi Adeleke ṣe wi, “Aarẹ Tinubu jẹ adari to yatọ pẹlu bo ṣe koju awọn ipenija to ti fi ọpọ ọdun fa orileede yii sẹyin, to si n la ọna ọjọọwaju to dara.

‘Labẹ idari rẹ, orileede Naijiria n bọ ninu iwa inakunaa, ati fifi nnkan ijọba ṣofo, o si n gbe awọn igbesẹ fun ilọsiwaju ati idagbasoke orileede yii.

“Lorukọ gbogbo awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun, mo ki Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, mo si gboṣuba fun un fun idari rere to n pese fun orileede yii.”

Gomina Adeleke waa gbadura fun Aarẹ pe yoo ṣe ọpọ ọdun laye ninu ilera pipe lati le tubọ gbe orileede yii doke agba.

Leave a Reply