Iya ọna meji: Lẹyin ti wọn ja baale ile kan lole tan, awọn adigunjale tun fipa ba iyawo rẹ sun niṣoju ẹ

Adewale Adeoye

Mẹta lara awọn adigunjale kan ti wọn lọọ ja Ọgbẹni Mudan Ibrahim, to n gbe lagbegbe Chori, nijọba ibilẹ Ringim, nipinlẹ Jigawa, lole, ti wọn tun fipa ba iyawo rẹ sun lọwọ awọn ọlọpaa agbegbe naa ti tẹ bayii.

Awọn mẹta ọhun ni: Ọgbẹni Abubarkar Isah, Ọgbẹni Umar Ibrahim ati Ọgbẹni Umar Nasara, ti gbogbo wọn n gbe lagbegbe Ringim kan naa.

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago meje aṣaalẹ ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, ni awọn ọdaran ọhun ya wọ inu ọgba ile Mudan, to wa lagbegbe Chori, ti wọn si ji apo ata wẹwẹ marun-un gbe. Lẹyin ti wọn ji ata rẹ tan ni ọkan lara awọn oniṣẹ ibi naa ba tun nawọ mu iyawo to ṣẹṣẹ fẹ tọjọ ori rẹ ko ju ogun ọdun lọ, wọn fipa ba a sun niṣoju ọkọ rẹ, lẹyin naa ni wọn sa lọ.

Ọga ọlọpaa patapata nipinlẹ naa, C.P A.T Abdullah, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun yii, sọ pe Ọgbẹni Mudan ti wọn ba iyawo rẹ sun niṣoju rẹ lo waa fọrọ ọhun to awọn ọlọpaa leti, tawọn si tete bẹrẹ iwadii abẹnu nipa iṣẹlẹ ọhun.

O ni, ‘‘Ni nnkan bii aago meje aṣaalẹ ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹta, ọdun yii, ni awọn ọdaran ọhun lọọ ja Mudan lole nile rẹ, gbogbo wọn ni wọn mu ada oloju meji dani, wọn ji ata apo marun-un gbe, wọn tun fipa ba iyawo ile rẹ sun niṣoju ọkọ rẹ. Mudan yii lo waa fọrọ ọhun to awọn ọlọpaa agbegbe naa leti, a ṣewadi nipa isẹlẹ ọhun, a si ti fọwọ ofin mu awọn ọdaran ọhun nibi ti wọn wa. Awọn paapaa ti jẹwọ pe loootọ lawọn huwa laabi ọhun.

Ọga ọlọpaa ni awọn maa too foju gbogbo wọn bale-ejọ.

 

Leave a Reply