Mọto to n ko awọn to n lọọ ṣọdun Ajinde nijamba, eeyan marundinlaaadọta lo ku

Adewale Adeoye

Ina lo jo awọn arina-ajo kan ti wọn n lọọ ṣọdun Ajinde gburugburu niluu Limpopo, lorileede South Africa. L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun yii, niṣẹlẹ naa waye lasiko ti awọn arina-ajo ti wọn jẹ aadọta ọhun gbera lati ilu Gaborone, lorileede Botswana, ti wọn n lọ sorileede South Africa, fun ti ajọdun Ajinde ọdun yii. Ṣugbọn niṣe ni ọkọ akero kan to n ko gbogbo wọn lọ ja sinu koto nla kan to wa lagbegbe Mamatlakala, lojuna marosẹ Mokopane, nijọba ibilẹ Limpopo, lorileede South Africa, ti awọn bii marundinlaaadọta ninu awọn ero naa si ku loju-ẹsẹ. Awọn kọọkan ti ko ku wa nileewosan ijọba orileede naa bayii ti wọn n gba itọju lọwọ.

ALAROYE gbọ pe dẹrẹba ọkọ akero ọhun lo ṣe aṣiṣẹ lasiko to n wa ọkọ ọhun lọ, nibi to ti n du ọwọ ọkọ naa lo ti ja sinu koto nla kan, ti ọkọ ọhun si gbana loju-ẹsẹ, eyi to mu kawọn eeyan naa jona ku.

Awọn tiṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ loju wọn sọ pe nitori pe loju-ẹsẹ ti mọto ọhun ja si koto lo gbana lo ṣe soro fawọn lati doola ẹmi awọn arina-ajo ọhun lasiko ti iṣẹlẹ ọhun waye.

Nibi tawọn kan si ti n gbiyanju lati jade nibẹ ni ina ọhun tun ka wọn mọ, ti wọn si jona deeru, ṣugbọn ori ko ọmọ oṣu mẹjọ kan yọ lọwọ iku ojiji naa.

Minisita fun igboke-gbodo ọkọ lorileede South Africa, Ọgbẹni Sindisiwe Chikunga, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin orileede ọhun lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun yii, sọ pe ibanujẹ nla gbaa ni iṣẹlẹ ọhun jẹ fawọn alaṣẹ ijọba orileede South Africa, paapaa ju lọ nigba to jẹ pe orileede awọn ni awọn arina-ajo ọhun n bọ lati waa ṣajọdun Ajinde, ko too di pe iṣẹlẹ laabi naa waye.

O fi kun ọrọ rẹ pe awọn maa too da oku gbogbo awọn to padanu ẹmi wọn ninu ijamba naa pada sorileede Botswana, ki awọn ẹbi wọn le ṣeto isinku wọn lọna ti wọn fẹ.

 

Leave a Reply