Eyi le o! Awọn ẹlẹwọn jẹ majele mọ ounjẹ, awọn mẹfa ti wa nileewosan

Adewale Adeoye

Mẹfa lara awọn ẹlẹwọn kan ti wọn jẹ majele mọ’nu ounjẹ ti wọn jẹ lorileede Gẹẹsi ni wọn ti sare gbe lọ sileewosan, ti wọn si wa lẹsẹ-kan-aye, ẹsẹ-kan-ọrun, nibi ti wọn ti n gbatọju bayii.

Ọgba ẹwọn kan ti wọn n pe ni Lewes, to wa lagbegbe Sussex, lorileede Gẹẹsi, ni iṣẹlẹ ọhun ti waye l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii.

ALAROYE gbọ pe inu ounjẹ kan tawọn alaṣẹ ọgba ẹwọn ọhun fun awọn ẹlẹwọn ọhun ni majele ọhun wa, bi wọn si ṣe jẹ ẹ tan ni wọn ti bẹrẹ si i lọ inu mọlẹ, ti awọn kọọkan si n yagbẹ gbuurugbu. Kawọn alaṣẹ si too mọ ohun to n ṣẹlẹ, mẹfa ninu awọn ẹlẹwọn ọhun ti dẹnu kọlẹ, kia ni wọn si ti gbe wọn lọ sileewosan ijọba kan to wa lagbegbe naa fun itọju.

Alukoro ileeṣẹ ọgba ẹwọn ọhun to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun yii, sọ pe awọn ti gbe gbogbo awọn ẹlẹwọn ọhun lọ sileewosan fun itọju. Bakan naa lo ni iwadii n lọ lọwọ nipa iṣẹlẹ ọhun, tawọn si maa mọ ohun to fa a ti majele fi wa ninu ounjẹ ti wọn jẹ.

Leave a Reply