Wọn mu akanda ẹda to n ṣowo egboogi oloro l’Ekoo

Wn mu akanda ẹda to n owo egboogi oloro l’Ekoo

Adewale Adeoye

Ọdọ awọn ọlọpaa agbegbe Akinpẹlu, niluu Oshodi, ipinlẹ Eko, ni akanda ẹda kan, Ọgbẹni Adamu Ileyasu, ẹni ọdun mejilelọgọta, to n ṣowo egboogi oloro laarin Oshodi, nipinlẹ Eko wa bayii. Ohun ti wọn tori ẹ ju u sakolo ọlọpaa ni pe o n ta egboogi oloro fawọn onibaara rẹ kan.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, S.P Benjamin Hundeyin, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun yii, sọ pe awọn owuyẹ kan ti wọn mọ nipa iṣẹ ti ko bofin mu ti Adamu n ṣe ni wọn waa fọrọ rẹ to awọn ọlọpaa agbegbe Akinpẹlu leti, tawọn yẹn si tete lọọ fọwọ ofin mu un. Lasiko ti wọn wa  alọ sile to n gbe ọhun ni wọn ba obitibiti igbo lọwọ rẹ.

Alukoro ni awọn n ṣewadi nipa rẹ lọwọ, tawọn si maa wọ ọ lọ si kootu tawọn ba ti pari.

 

Leave a Reply