Wahala n bọ o, awọn ijoye Olubadan kọ lati yọju sibi ipade ti Ladọja pe lati yan Olubadan tuntun

Ọlawale Ajao, Ibadan

Bo tilẹ jẹ pe gbogbo aye lo ti mọ ẹni to kan bayii lati jẹ Olubadan ilẹ Ibadan, o ti daju gbangba bayii pe yoo pẹ diẹ ki wọn too le j’ọba ilu naa lasiko yii nitori awọn akude kan to wọ ọrọ ọba jijẹ ọhun. ALAROYE gbọ pe ẹni ti ipo ọhun kan ko ti i ṣetan lati jọba nitori aisan ti wọn lo da baba naa gbalẹ, bẹẹ, niwọn igba to ba ṣi wa laye, bi ko ba jẹ Olubadan, ẹlom-in ko le jẹ.

Gẹgẹ bii eto ati ilana ti wọn fi n jọba ilu naa,

Ọba Akinloye Owolabi Ọlakulẹhin, ti i ṣe Balogun ilẹ Ibadan lọwọlọwọ lo kan bayii lati gori itẹ Olubadan lẹyin ipapoda Ọba Mohood Ọlalekan Balogun, ẹni to gbesẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii.

Sibẹsibẹ, gẹgẹ bi wọn ṣe n ṣe e, awọn agbaagba ijoye, ti wọn tun jẹ afọbajẹ ilẹ Ibadan, ni lati kọkọ ṣepade, ki wọn si fọwọ si i pe awọn fara mọ ki onitọhun gori itẹ gẹgẹ bii Olubadan tuntun.

Lọdun to kọja (2023),  ni Olubadan to gbesẹ yii, Ọba Mahood Lekan Balogun, sọ awọn agba ijoye Ibadan di ọba alade. Nibi gan-an ni wahala ti kọ bẹrẹ lori akitiyan lati fi Olubadan jẹ.

Idi ni pe nigba ti Ọba Balogun sọ wọn di ọba alade lọjọ keje, oṣu Keje, ọdun 2023, Sẹnetọ Rashidi Ladọja, ti i ṣe Ọtun Olubadan, kọ lati jọba, o ni ọba kan ṣoṣo to wu oun i jẹ ko ju Olubadan ilẹ Ibadan lọ. Bẹẹ lawọn agba ijoye mẹwaa yooku di kabiesi, ti Ladọja nikan si duro sipo Agba-Ijoye ti gbogbo wọn ti jọ wa tẹlẹ.

Ipinnu ti Ladọja ṣe nigba naa lo di nnkan to ti n koba a bayii, nitori nigba ti asiko to fun awọn afọbajẹ Ibadan lati fọwọ siwee pe awọn fara mọ pe ki Ọlakulẹhin jẹ Olubadan, awọn yooku dẹyẹ si i, wọn ni ko lẹtọọ lati jokoo ṣepade pẹlu awọn, nitori ọba alade lawọn nigboro Ibadan, ijoye lasan lasan si loun (Ladọja) jẹ.

Gẹgẹ bii aṣa ti wọn fi n jẹ Olubadan, lẹyin ti wọn ba ti ṣadura ọjọ kẹjọ ipapoda ọba to waja lawọn agbaagba ijoye, ta a tun mọ si igbimọ Olubadan, yoo fẹnu ko lori iyansipo ẹni ti ọba kan. Ijoye to ba si dagba ju lọ lẹyin ẹni ti ipo ọba kan ni yoo pe iru ipade bẹẹ.

Niwọn igba to jẹ pe Ọtun Olubadan lo ga nipo ju lọ ninu awọn agba oye, oun lo pe awọn ijoye yooku sipade ninu aafin Olubadan to wa l’Ọja’ba, n’Ibadan, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrindilọgbọn (26), oṣu Kẹta, ọdun yii.

Ṣugbọn niṣe lawọn oloye yooku dágunlá si ipade naa, Agba-Oye Ladọja to pepade ọhun lo nikan da nnkan rẹ ṣe.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ yii ninu ifọrọwerọ pẹlu akọroyin wa, Ẹkẹrin Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Amidu Ajibade Salaudeen, fidi ẹ mulẹ pe loootọ, gbogbo awọn ni Ladọja fiwe pe síbi ìpàde, ṣugbọn lati ọjọ Aje, Mọnde, to ṣaaju ọjọ naa lawọn ti ṣe eyi to jẹ ojulowo ìpàdé, ati pe niṣe lawọn mọ-ọn-mọ kọ lati lọ sibi ipade ti wọn fi si ọjọ Iṣẹgun, nitori ẹni to pepade ọhun ki i ṣe ọba.

Gẹgẹ bo ṣe sọ,”Ẹgbọn mi Rashidi Ladọja ni ọtun Olubadan. Ṣugbọn bi awa ta a jẹ ọba alade la ṣepade lọjọ Mọnde. Oloye agba lawọn, wọn o ba wa gba ade. Iyẹn lo fa a to fi jẹ pe a o le jokoo ṣepade pọ pẹlu wọn. Oloye o le maa pe ọba sibi ipade, ko ṣee ṣe. Loootọ ni wọn ga ju wa lọ ninu ilana ta a fi n joye nilẹ Ibadan, ṣugbọn awa ni ipo ju wọn lọ”.

Nigba to n sọrọ lori idi to fi ṣe e ṣe ko pẹ ki Ibadan too le jọba tuntun, Ọba Ajibade fidi ẹ mulẹ pe “a o ti i fi oju kan Ọba Ọlakulẹhin. A lọ sile wọn lẹyin ti wọn sinku Ọba Balogun tan, ọmọ wọn ta a ba sọ pe wọn o si nile. Titi doni ti mo n ba yin sọrọ yii a o ti i foju ṣe meji wọn.

“Bi baba wa, Ọlakulẹhin ba ṣetan (lati jẹ Olubadan), wọn yoo ranṣẹ pe wa pe awọn ti ṣetan o. Nigba naa la a jọ jokoo ṣepade pọ, ti awa igbimọ ọba Ibadan yoo si dibo yan wọn gẹgẹ bii Olubadan tuntun.

“Mi o mọ boya bọọda mi, Ladọja, yoo le kunju oṣunwọn lati kopa ninu ipade yẹn, nitori agba ijoye lawọn ni tiwọn, wọn ko si ninu igbimọ awa ọba ilẹ Ibadan, afi ti gomina funra rẹ ba sọ pe oun fẹ ki wọn ba wa kopa ninu ẹ nikan lo ku, nitori ijọba lalaṣẹ lori gbogbo wa”.

Nigba to n fi aidunnu ẹ han nipa bi awọn ijoye Olubadan yooku ko ṣe yọju sipade to pe, Agba-Oye Ladọja, sọ pe oun yoo pe ipade mi-in. Ṣugbọn ti gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹ ri yii ba tun pe ipade mi-in, ko daju pe awọn eeyan naa yoo tun yọju.

 

Leave a Reply