O digba ta a ba ṣe ohun to yẹ ka ṣe ki iṣoro aabo yii too dopin – Babangida

Faith Adebọla

 Olori orileede yii laye ologun, Ajagun-fẹyinti Ibrahim Babangida, ti sọ ero rẹ lori iṣoro aabo to mẹhẹ to n koju orileede yii lọwọlọwọ, o ni o digba ti ijọba ba ṣe ohun to yẹ ki wọn ṣe ki iṣoro naa too re odo lọọ mu’mi.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo wo kan to ṣe lede Hausa, lọjọ Aiku, Sannde yii, Babangida ni wahala awọn janduku agbebọn, ajinigbe ati ti Boko Haram ki i ṣe iṣoro ti a ko le bori bi ijọba ba pinnu lati bori ẹ, ti wọn si gbe igbesẹ to yẹ ki wọn gbe.

Lara igbesẹ ti Babangida lo pọn dandan funjọba lati gbe ni ki wọn ra awọn nnkan ija igbalode fawọn jagunjagun wa, ki wọn si fun wọn ni idalẹkọọ lori bi wọn ṣe maa lo o. O lawọn ologun wa ko le bori iṣoro aabo pẹlu nnkan ija to wa lọwọ wọn bayii, tori awọn nnkan eelo wọn ko bode mu mọ, ko si kunju oṣuwọn to.

Babangida ni: “Bẹẹ ni, awọn ologun wa nilo nnkan ija tuntun, to bode mu. Ṣugbọn wọn tun nilo idalẹkọọ lori bi wọn ṣe maa lo o, ki i ṣe ka kan ko nnkan ija tuntun fun wọn lai mọ lilo ẹ, a gbọdọ kọ wọn ni.

A tun gbọdọ fọwọ sowọ pọ pẹlu awọn ologun wa, a gbọdọ wa niṣọkan, ka si ṣatilẹyin fawọn adari wa, ki gbogbo wa ni afojusun kan naa. Laarin awọn adari ati araalu, iṣọkan ati alaafia gbọdọ wa, ti ko ba si, a o le bori awọn ipenija wọnyi. Mo ranti pe ọdun mẹta la fi jagun abẹle, awọn araalu ṣugbaa ijọba lasiko yẹn, ijọba naa si ṣe gbogbo nnkan ti wọn le ṣe, wọn pese nnkan eelo to yẹ, awọn ti wọn jagun yẹn gbagbọ pe iṣọkan orileede yii lo ṣe pataki ju lọ, a si ṣaṣeyọri.”

Babangida tun sọ pe loorekoore loun maa n gba ijọba to wa lode yii lamọran, oun ki i pariwo ẹ sita ni. O ni ko sigba toun ki i fun wọn ni iṣiti ati amọran to yẹ, ṣugbọn ọtọ ni ka gbaayan lamọran ọtọ ni konitọhun ṣiṣẹ lori ẹ bo ṣe yẹ.

Ṣugbọn ẹgbẹ ajijangbara ilẹ Yoruba nni, Afẹnifẹre ti sọrọ lori amọran ti Badamọsi Babangida loun n gba ijọba apapọ yii, wọn ni fifi akoko ṣofo lo jẹ lati gba Buhari lamọran, tori Aarẹ wa ki i gbamọran, ko si ni i tẹle e.

Adari ẹgbẹ naa, Oloye Ayọ Adebanjọ, sọ nirọlẹ ọjọ Aiku pe “Ki lo de ti Babangida n dibọn, ṣe o maa loun o mọ Buhari ni? Afi ti Babangida ba fẹẹ purọ lo ku, ko le sọ pe oun ko mọ pe Aarẹ Babangida ki i tẹle amọran ti wọn ba gba a, tinu ẹ lo maa n ṣe, tori naa, bii ẹni to n pọnmi sinu apẹrẹ lo jẹ lati sọ peeyan n gba ijọba yii lamọran, ifakoko ṣofo lasan ni.”

Leave a Reply