O ma ṣe o, akẹkọọ Fasiti Adekunle Ajasin gbe majele jẹ l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọkan ninu awọn akẹkọọ Fasiti Adekunle Ajasin to wa niluu Akungba Akoko, Fẹranmi Fasunle Akinwumi, ti binu pa ara rẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii lai sọ idi to fi ṣe bẹẹ fun ẹnikẹni.

Ọmọwumi to wa ni ipele keji lẹka ti wọn ti n kọ nípa imọ oṣelu la gbọ pe o po majele tawọn eeyan mọ si sinipaasi mọ gaari lọjọ naa, to si gbe e mu ninu yara ile to n gbe l’Akungba Akoko.

Ẹnikan tiṣẹlẹ naa ṣoju rẹ ṣalaye fawọn oniroyin pe ọmọbinrin naa ko ti i ku nigba tawọn kọkọ de ibi tó wa, leyii to mu ki awọn gbe e digbadigba lọ sileewosan alabọọde kan to wa nitosi.

O ni lati ibẹ ni wọn ti gba awọn nimọran pe kawọn tete maa gbe e lọ si ọsibitu ijọba to wa ni Ikarẹ Akoko, nigba ti wọn ko tun ri i tọju nibẹ lo ni awọn tun sare gbe e lọ sileewosan ijọba apapọ (FMC), niluu Ọwọ.

Ibi ti wọn ti n mura ati tun gbe e kuro nibẹ ki wọn si mori le ileewosan ẹkọsẹ iṣegun Fasiti Afẹ Babalọla to wa l’Ado-Ekiti, lọmọbinrin naa ti dakẹ.

Leave a Reply