Faith Adebọla
Gbajugbaja irawọ oṣere tiata ilẹ wa nni, Ojo Arowoṣafẹ, ti gbogbo eeyan mọ si Fadeyi Olori, ti jade laye.
Ọkunrin naa mi eemi ikẹyin ni ile rẹ to wa lẹyin oko Ọbasanjọ, iyẹn Ọbasanjọ Farms, niluu Ọta, nipinlẹ Ogun.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ọkan ninu awọn to n ṣetọju gbajumọ onitiata yii lo lọọ ṣabẹwo si i lowurọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ keje, oṣu Kẹta yii, gẹgẹ bii iṣe rẹ lati mọ ipo ti ilera baba naa wa, ko too maa ba tirẹ lọ. Amọ nigba to de ile naa, titipa ni ilẹkun wa, ko si jọ pe baba naa ti i jade bọ sita laaarọ ọjọ Tusidee yii.
Ọkunrin yii sọ f’ALAROYE pe oun pe baba gẹgẹ boun ṣe maa n pe wọn, ti wọn si maa n da oun lohun, ṣugbọn lọtẹ yii, oun ko gburoo kan, o loun kanlẹkun titi, sibẹ ẹnikẹni ko fesi, eyi lo mu kara fu oun pe iru oorun asunwọra wo ni Fadeyi sun yii. Lo ba lọọ ke si ọmọ baba naa ati ọkọ rẹ nile tawọn n gbe ti ko fi bẹẹ jinna sile Fadeyi, gbogbo wọn si jọ da rẹi-rẹi lọ sibẹ.
Nigba ti wọn gbalẹkun titi tẹnikan o fesi, wọn ni lati ja ilẹkun naa, wọn si ba Ojo Arowoṣafẹ lori ibusun rẹ, amọ ki i ṣe oorun lo sun, akukọ ti kọ lẹyin ọmọkunrin ni.
Wọn gbe e lọ sileewosan ijọba to wa ni Ọta, ibẹ ni dokita ti fidi ẹ mulẹ fun wọn pe Fadeyi Oloro ti ku.
Ṣa, wọn ti gbe oku rẹ lọ sile iṣokulọjọ Omega Motuary, ni Sango.
Wọn lawọn mọlẹbi yoo maa kede bi eto isinku yoo ṣe lọ si laipẹ!