O ma ṣe o, ile-ẹjọ sọ ọkọ, iyawo ati iyaayawo sẹwọn ọgọta ọdun l’Ekiti

Taofeek SurdiqAdo-Ekiti

 Boya bi wọn ba mọ pe ibi tọrọ awọn maa ja si nile-ẹjọ ree, boya wọn iba ti ma lọwọ ninu iwa jibiti ti wọn lu yii, ṣugbọn abamọ ki i ṣaaju ọrọ, tori ile-ẹjọ giga ipinlẹ Ekiti kan ti paṣẹ pe ki Ọgbẹni Ebenezer Adeolu Alongẹ, iyawo  ẹ, Isakunle Ọlamide Oyinlọla, ati iya iyawo ẹ, Abilekọ Isakunle Eunice Moradekẹ, lọọ fẹwọn ọgọta ọdun jura.

Gẹgẹ bi Alukoro ajọ EFCC, Ọgbẹni Wilson Uwajurẹn, ṣe wi, o ni ẹsun mejila ọtọọtọ ni ajọ naa ka sawọn afurasi ọdaran naa lẹsẹ nile-ejọ giga ipinlẹ Ekiti to fikalẹ siluu Ado-Ekiti, awọn si ti wa lẹnu ẹjọ naa lati ọdun mẹta sẹyin ki idajọ too ṣẹṣẹ waye lori ẹ lọjọ Ẹti, Furaidee yii.

O ṣalaye pe iṣẹ awọn to n gbowo tabi sanwo fun kọsitọma lori kanta, tawọn eleebo n pe ni kaṣia (cashier) ni Ebenezer n ṣe ni ọkan lara awọn banki to lookọ nilẹ wa, ṣugbọn ti wọn forukọ bo laṣiiri.

Ohun to ṣẹlẹ gẹgẹ bo ṣe wi ni pe, lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu keji, ọdun 2018, Ebenezer Alongẹ gba miliọnu mejilelọgọta o le irinwo naira (#62,400,000) wọle latọdọ kọsitọma kan, ṣugbọn kaka ko kowo naa sinu akaunti kọsitọma ọhun, ko ṣe bẹẹ, ọtọ ni ibi to dari owo si.

Nigba ti kọsitọma reti titi, ti ko ri ẹri pe owo ti wọle sakaunti oun niyẹn ba lọọ fẹjọ sun ni banki, o si ko awọn iwe ẹri to fihan pe loootọ loun sanwo wọle lọjọ naa dani.

Banki lo fọrọ ọhun to ajọ Economic and Financial Crimes Commission (EFCC) ẹka ti Ibadan leti, pe ki wọn waa ba awọn tanna wodi iṣẹlẹ ọhun, lọgan si ni iwadii bẹrẹ.

Iwadii ọhun lo tu aṣiri pe Alongẹ lo gbowo lọwọ kọsitọma loootọ, o si buwọ lu u pe oun gbowo, iwadii tun fihan pe niṣe lo dari ele ori owo naa tiye rẹ n lọ si miliọnu mọkanlelogun naira (#21 million) sinu akaunti iyawo rẹ, Ọlamide.

Lẹyin eyi lo tun dọgbọn tọju awọn owo to gba lọwọ awọn kọsitọma mi-in sinu akaunti iya-iyawo rẹ, Eunice Moradekẹ.

Miliọnu mọkanlelogun lowo olowo ti wọn lawọn mẹtẹẹta fi ṣara rindin, wọn lọkunrin naa ti kọle ringindin siluu Ado-Ekiti lara owo ọhun.

Agbẹjọro fun ijọba, Ọgbẹni Abdulrasheed Lanre Suleiman, atawọn lọọya mi-in ti wọn ṣoju fun EFCC fidi ẹ mulẹ pe loootọ niṣẹlẹ naa waye, ati pe ko ṣeeṣi, niṣe lawọn afurasi mẹtẹẹta naa diidi lu awọn kọsitọma banki ọhun ni jibiti. Wọn pe ẹlẹrii meji lati ta ko awọn afurasi ọdaran naa, wọn si ko ọpọ ẹsibiiti da silẹ pẹlu.

Lara ẹsun mejila ti wọn fi kan awọn afurasi naa ni pe wọn lu jibiti, wọn jale, wọn feru gba ohun ti ki i ṣe tiwọn, wọn si tun gbimọ-pọ lati huwa buruku. Wọn lawọn ẹsun wọnyi ta ko isọri okoodinnirinwo ati mẹwaa (390) apa kẹsan-an iwe ofin iwa ọdaran tọdun 2012 ti ipinlẹ Ekiti n lo.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidaajọ Adekanye Ogunmoye sọ pe olupẹjọ ti fi ẹri to pọ to han, ko si ruju rara pe loootọ lawọn olujẹjọ naa huwa buruku ọhun. O lawọn mẹtẹẹta nile-ẹjọ yii da lẹbi awọn ẹsun mejila ti wọn fi kan wọn.

Adajọ Ogunmoye paṣẹ pe ki ọkọọkan wọn lọọ faṣọ penpe roko ọba lẹwọn fun ọdun marun-un marun-un lori ẹsun kọọkan, eyi ti aropọ rẹ jẹ ọgọta ọdun ẹni kọọkan wọn, bo tilẹ jẹ pe, bo ṣe wi, wọn maa ṣẹwọn ọdun marun-un marun-un naa papọ ni, ki wọn si bẹrẹ si i ka a fun wọn latọdun 2018 ti wọn ti wa lakolo awọn agbofinro, o si tun paṣẹ pe ki wọn ta ile ti Alongẹ kọ, atawọn dukia mi-in to jọju, ki wọn fi di gbese jibiti to lu.

O ni eyi maa jẹ arikọgbọn fawọn mi-in ti wọn ba fẹẹ daṣa palapala bii eyi.

Leave a Reply