O ma ṣe o, kọntena tẹ ọmọọdun mẹfa pa sibudokọ Iyana Isọlọ

Faith Adebọla, Eko

Ọmọ meji, tẹgbọn-taburo, ni baba kan fa lọwọ nigba to n jade nile laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹsan-an yii, wọn fẹẹ jọ debikan ni, ṣugbọn ibudokọ Iyana Isọlọ ti wọn duro si lati wọ bọọsi ibi ti wọn n lọ ọhun ni tirela to gbe kọntena kan ti ya bara lojiji lori ere, kọtena to gbe sẹyin ja bọ, o tẹ ọmọ kan pa lẹsẹkẹsẹ, o si ṣe baba naa, ati ọpọ eeyan, leṣe.

Ba a ṣe gbọ, obinrin kan to n ta nnkan mimu lodikeji ibudokọ naa, Abilekọ Feyin, sọ pe iṣẹlẹ naa ṣoju oun, o ni ori titi marosẹ Oṣodi si Apapa ni tirela naa n tọ bọ pẹlu ere buruku,  ki bọọṣi akero Faragon kan too gbemu jade si i lojiji.

Bọọsi yii lo ni tirela naa pẹwọ fun, ṣugbọn bo ṣe ya bara lori ere, niṣe ni kọntena ẹyin rẹ yẹ, lo ba ja bọ lu ọmọkunrin to doloogbe naa. O ni kọntena naa rọ ọpọ eeyan da si kọta to wa leti ibudokọ ti wọn duro si ọhun.

“Ko sẹni to le ya fọto iṣẹlẹ yii, tori niṣe ni gbogbo wa n wa ẹkun mu, agaga nigba ti aburo mi, Baba Ṣẹwa, to n ṣe agbero nibudokọ naa bẹrẹ si i fa awọn eeyan jade, ọpọ lo fara gbọgbẹ yanna-yanna, niṣe la bẹrẹ si i bẹ awọn onimọto lati ba wa gbe wọn lọ sọsibitu, tori awọn kan ti da lapa, lẹsẹ ninu wọn. Nigba ti wọn fa oku ọmọkunrin naa jade ninu gọta, ariwo ati igbe ẹkun lawọn eeyan bu si,” gẹgẹ bo ṣe wi.

Alukoro ajọ LASEMA to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ.

Wọn ti ko awọn to fara pa naa lọ sọsibitu Jẹnẹra Isọlọ fun itọju pajawiri, oku ọmọ naa si ti wa ni mọṣuari.

O lawọn oṣiṣẹ ajọ naa ti n ba iṣẹ lọ lati yọ kọntena ọhun ati awọn ọkọ ti tirela yii kọ lu.

Leave a Reply