O ma ṣe o, Sẹnetọ Gbenga Aluko ku lojiji

Ọkan ninu awọn ọmọ ile-igbimọ aṣofin ilẹ wa tẹlẹ, Sẹnetọ Gbenga Aluko, la gbọ pe o ku lojiji lọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii.

Iroyin to tẹ ALAROYE lọwọ ni pe ko si ohun to ṣe ọkunrin naa, wọn lo ba awọn eeyan ṣere, o ba wọn sọrọ, awọn kan si ri i titi aago mẹrin irọlẹ ọjọ Abamẹta naa. Ojiji ni wọn ni ọkan ọkunrin naa daṣẹ silẹ, to si ku lojiji.

Sẹnetọ Gbenga Aluko to jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Ekiti yii ti figba kan jẹ igbakeji akojaanu ile nileegbimọ aṣofin agba niluu Abuja.

Leave a Reply