O ma ṣe o, wọn pa ọmọ Lemọọmu ilu Ajaawa sinu igbo

 

 

Ọlawale Ajao, Ibadan

Gbogbo araalu Ajaawa, nijọba ibilẹ Ogo-Oluwa, nipinlẹ Ọyọ, ni wọn n ṣọfọ lọwọ bayii pẹlu bi awọn ọdaju eeyan kan ṣe pa ọkunrin alapata kan, Amuda Lawal sinu igbo.

Ọkunrin ẹni ọdun mẹrinlelogoji to n ṣiṣẹ apata ẹran yii ni wọn pe lọmọ lemọọmu agba ilu Ajaawa.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrinla, oṣu karun-un, ọdun 2021 yii, ti i ṣe ọjọ keji ọdun Itunu Aawẹ to kọja yii ni wọn pe Lawal lati waa ra maaluu lagbo maaluu kan to gbajumo niluu naa.

Ṣugbọn alọ ọkunrin alapata naa ni wọn ri, wọn ko ri abọ rẹ, lati ọjọ naa ni wọn ko ti gburoo ẹ nile, loko ati nibikibi lẹyin odi ko too di pe wọn ri oku ẹ ninu igbo lọsan-an ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ti i ṣe ọjọ karun-un ti i wọn pa a.

Ninu igbo, lagbegbe ti ọpa epo gba kọja niluu Ajaawa ni wọn ti ri oku ẹ, eyi to ti n jẹra sibi ti wọn pa a si nibẹ.

Awọn ọlọpaa ni wọn jẹ ki awọn ẹbi Lawal mọ ipo to wa yii nitori awọn agbofinro lẹni to kọkọ ri oku naa lọọ fiṣẹlẹ ọhun to leti.

Tẹ o ba gbagbe, nibikan niluu Ajaawa yii kan naa lawọn ajinigbe ti ji eeyan mẹsan-an gbe lẹẹkan naa ni nnkan bii ọsẹ meji sẹyin.

 

Leave a Reply