O ma ṣe o, dokita ti wọn yinbọn fun lasiko tawọn afẹmiṣofo kọ lu reluwee to n lọ lati Abuja si Kaduna ti ku o  

Jọkẹ Amọri

Ọkan ninu awọn ti wọn ṣakọlu si lasiko ti awọn afẹmiṣofo kọ lu reluwee to n na Abuja si Kaduna, ninu eyi ti awọn eeyan to fẹẹ to ẹgbẹrun kan wa, Dokita Chinelo Megafu, ti ku o.

Awọn ọrẹ ọmọbinrin to jẹ dokita to maa n tọju awọn eleyin naa lo kọ ọ sori ikanni agbọrọkaye wọn lori Instagraamu pe ọmọbinrin naa wa ninu awọn to kagbako ijamba lọwọ awọn afẹmiṣofo ti wọn da ọkọ reluwee ti wọn wọ lọna ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.

Lasiko akọlu naa ni ọmọbinrin yii fi ọrọ ranṣẹ latori tuita rẹ pe oun wa ninu tireeni naa, ati pe wọn ti yinbọn mọ oun, ki awọn eeyan maa gbadura fun oun.

Ọsibitu ti wọn gbe ọmọbinrin naa lọ lo ku si.

Bakan naa ni igbakeji gomina ipinlẹ Zamfara tẹlẹ, Ibrahim Wakkala naa wa ninu awọn to ni ijamba lasiko ti awọn afemiṣofo kọ lu tireeni naa, ṣugbọn oun ko ku, bo tilẹ jẹ pe o fara pa, to si wa nileewosan to n gba itọju.

Lalẹ ọjọ Aje ni wọn ni awọn afẹmiṣofo kọ lu reluweee naa ni agbegbe Katari ati Rijana, nipinlẹ Kaduna.

ALAROYE gbọ pe niṣe ni awọn eeyan naa bẹrẹ si i yinbọn lakọ lakọ lai dawọ rẹ duro si reluwee to fẹrẹ ko to eeyan bii ẹgbẹrun kan yii.

Lasiko naa ni ọpọ ninu awọn ero naa fara gbọgbẹ, ti wọn si tun ji awọn kan ko lọ ninu wọn.

Dokita yii wa ninu awọn ti ibọn ba, o si gbe e sori ikanni rẹ pe ki awọn eeyan fi adura ran oun lọwọ, ṣugbọn o ṣe ni laaanu pe ọmọbinrin arẹwa naa pada jade laye.

Oṣu to kọja yii la gbọ pe ọmọbinrin naa kọwe fipo silẹ ni ọsibitu to ti n ṣiṣẹ. Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, lo yẹ ko tẹ ọkọ leti lọ siluu oyinbo, nibi to fẹẹ wa iṣẹ aje lọ, gẹgẹ bi ọkan ninu awọn ẹlẹgbẹ rẹ ṣe gbe e sori ikanni rẹ, to si waa ku lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ.

Yatọ si dokita yii, a gbọ pe meji ninu awọn to maa n tọju inu reluwee naa, Loretta ati Abdul, naa jade laye, ti wọn si ti gbe oku wọn lọ sileewosan kan ti wọn n pe ni St Gerald’s Catholic Hospital, niluu Kaduna.

 Titi di ba a ṣe n sọ yii ni wọn ṣi n wa awọn ero inu ọkọ rẹluwee ti wọn ji gbe ọhun, bo tilẹ jẹ pe awọn agbofinro ti fọn sinu igbo, ti wọn si ti ri awọn kan ninu wọn gba pada.

 

Leave a Reply