O ma ṣe o, idile kan parun sinu ijamba ọkọ

Adewale Adeoye

Beeyan ba jori ahun, to ba ri bi ijamba ọkọ  ṣe ṣeku pa idile kan, ninu eyi tiyaa ati ọmọ wa nibẹ, onitọhun aa bomi loju gidi ni.

Iṣẹlẹ laabi ọhun waye lọjọ kẹfa, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, ti wọn si ti ṣeto isinku wọn siluu wọn to wa lagbegbe Bare, nijọba ibilẹ Numan, nipinlẹ Adamawa, lọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹrin, ọdun yii.

Orukọ iya ati ọmọ ti wọn ku sinu ijamba ọkọ naa ni Abilekọ Oloogbe Anis Lois Bayero, ati ọmọ rẹ Oloogbe Sarah Basil Bayero.

ALAROYE gbọ pe nibi ode ariya kan ni wọn n lọ lọjọ kẹfa, oṣu yii, ṣugbọn lojuna marosẹ kan nipinlẹ Adamawa ni ijamba ọkọ naa ti waye, ti idile ọhun si parun sinu ijamba ọkọ ti wọn wa.

Leave a Reply