O ṣẹlẹ! Wọn fẹẹ wọ alaga APC,  Ganduje, iyawo ati ọmọ rẹ lọ si kootu, eyi lohun ti wọn ṣe

Adewale Adeoye

Gbogbo eto lo ti pari bayii lori bi awọn alaṣẹ ijọba ipinlẹ Kano ṣe maa foju Alhaji Umar Ganduje ti i ṣe alaga ẹgbẹ APC, iyawo rẹ, Abilekọ Hafsat Ganduje, ọmọ rẹ atawọn mẹfa mi-in bale-ẹjọ lori ẹsun iwa ọdaran ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku ti wọn fi kan wọn. Ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni igbẹjọ ọhun maa waye niwaju Onidaajọ Usman Na’ aba, tile-ẹjọ giga kan to wa niluu Kano.

ALAROYE gbọ pe niwaju adajọ ile-ẹjọ giga kan to wa niluu Kano, ni wọn maa foju wọn ba, ẹsun iwa ọdaran pe wọn gba riba owo dọla tiye rẹ jẹ ẹgbẹrun lọna irinwo o le diẹ ( $ 413, 000)  ati ṣiṣi ipo lo ni wọn fi kan Ganduje.

Ninu iwe ti wọn fi pe Alhaji Ganduje lẹjọ ni wọn darukọ awọn bii: Alhaji Abdullah Umar Ganduje ti i ṣe alaga ẹgbẹ APC, iyawo rẹ, Abilekọ Hafsat Ganduje, Ọgbẹni Abubarkar Bawuro, Umar Abdullah Umar, Jibilla Muhammad, ileeṣẹ kan ti wọn n pe ni Lamash Properties LTD, Safari Textile LTD, ati Lesage General Enterprise’ lẹjọ.

Awọn alaṣẹ ijọba ipinlẹ Kano ni awọn ti pese awọn ẹlẹrii mẹẹẹdogun silẹ ti wọn maa sọrọ ta ko awọn olujẹjọ, paapaa ju lọ lori ẹsun riba tawọn fi kan alaga ẹgbẹ APC naa.

Adajọ agba fun ipinlẹ Kano, Ogbẹni Haruna Isah Dederi, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹrin, ọdun yii, sọ pe awọn ṣetan lati foju Ganduje atawọn mẹfa tawọn fẹsun iwa ọdaran kan bale-ẹjọ lọjọ kẹtadinlogun, oṣu yii, ati pe gbogbo wọn pata lawọn ti fun niwee ipẹjọ ko ma baa ba wọn lojiji.

Atẹjade kan to fi sita lori iṣẹlẹ ọhun lọ bayii pe, ‘Ootọ ni pe a maa foju Alhaji Ganduje atawọn mẹfa mi-in bale-ẹjọ lọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii, lori ẹsun iwa ọdaran ta a fi kan wọn. Ṣugbọn ohun ti mi o mọ ni boya loootọ ni wọn ti fun wọn niwee ipẹjọ rara. Ko sọrọ ninu ohun ti Ganduje n sọ lẹnu yẹn pe oun ko lẹjọọ jẹ lọdọ ijọba ipinlẹ Kano, ko sẹnikan to kọja ofin, ẹkọ nla si leyi paapaa jẹ fawọn to n ṣi agbara lo nipo ti wọn wa bayii, ọjọ kan n bọ ti wọn aa fipo naa silẹ, ohun ti wọn ṣe n pada bọ waa di ọran si wọn lọrun.

Ẹsun ta a fi kan Ganduje, abẹ ofin ipinlẹ Kano lo ṣẹ si, ki i ṣe ijọba orileede Nigeria lo n ba a ṣẹjọ.

Bakan naa la si ti pẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun si ẹjọ ti adajọ Liman tile-ẹjọ giga kan niluu Abuja da lori ẹjọ Ganduje laipẹ yii.

Ko si ani-ani, a maa too foju Ganduje balẹ-ẹjọ laipẹ yii.

 

Leave a Reply