Wọn ti mu tọkọ-taya yii, ayederu ọti ni wọn n pọn faraalu mu

Adewale Adeoye

Ọdọ awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa Zone 2, ni awọn tọkọ-taya meji kan ti wọn n pọn ọti waini atawọn oriṣiiriṣii ọti ayederu mi-in, ti wọn si nta a fun araalu wa bayii, wọn n ran awọn agbofinro lọwọ ninu iwadii wọn lori ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Awọn tọkọ-taya ọhun ni Abilekọ Margret Austin ati Ọgbẹni Austin Idemudia, ti wọn n gbe lagbegbe Mubi Ọlawunmi Close, ni Ayetoro Itẹlẹ, nipinlẹ Ogun.

ALAROYE gbọ pe o ti le lọdun mẹfa sẹyin bayii ti wọn ti n pọn ọti ayederu naa ta fawọn araalu ko too di pe ọwọ tẹ wọn lọjọ kẹrin, oṣu Kẹrin, ọdun yii, nileeṣẹ ti wọn n lo fun iṣẹ ti ko bofin mu naa.

Lara awọn ọti waini ayederu ti wọn maa n ṣe sita ni awọn bii: Waini, bia, Ṣampeeni, atawọn oniruuru ọti ayederu mi-in.Yatọ sawọn ọti ayederu ti wọn ka mọ wọn lọwọ, oniruuru nnkan ti wọn n lo bii eroja lati fi ṣe awọn ọti yii bi: igo ofifo, arọ, maṣiini ti wọn fi n ṣe ọti naa atawọn nnkan mi-in ni wọn ba lọwọ wọn.

Alukoro ẹka ileeṣẹ ọlọpaa Zone 2, S.P Ayuba T Umma, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Iṣegun, Tusidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹrin, ọdun yii, sọ pe ikọ akanṣe ọlọpaa ti C.S.P Ngozi Braide, ṣaaju ni wọn lọọ fọwọ ofin mu awọn afurasi ọdaran ọhun lẹyin tawọn araalu kan waa ta wọn lolobo nipa iṣẹ laabi ti wọn n ṣe.

Lẹyin ti wọn fọwọ ofin mu wọn tan ni Abilekọ Margret jẹwọ fawọn ọlọpaa pe awọn ti wa lẹnu iṣẹ  naa lati nnkan bii ọdun mẹfa sẹyin, tawọn si n ta a fawọn onibaara awọn ti wọn wa niluu Eko ati ipinlẹ Ogun.

Lori iṣẹlẹ ọhun, Ọga agba Zone 2, A.I.G Ọlatoye Durosinmi, gba awọn araalu nimọran pe ki wọn maa woye ayika wọn, ki wọn si tete maa sọrọ awọn oniṣẹ ibi to ba wa laarin ilu fawọn ọlọpaa,

O ni laipẹ yii lawọn maa foju awọn tọkọ-taya meji naa bale-ẹjọ lẹyin tawọn ba pari iwadii awọn lori wọn, ki wọn le jiya ẹṣẹ ti wọn ṣẹ.

Leave a Reply