O ma ṣe o, ọkọ akoyọyọ tẹ ọlọkada kan pa l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọmọkunrin kan lọkọ akoyọyọ tun tẹ pa lori ọkada niluu Ondo, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii.

Iṣẹlẹ ọhun lo waye nibi kan ti wọn n pe ni Iyana Oke-Igbala, Odojọmu, ni nnkan bii aago meji ọsan ọjọ naa.

ALAROYE fidi rẹ mulẹ nipa iṣẹlẹ naa pe igunkugun ti ọmọkunrin ti ko ti i ju bii ẹni ogun ọdun lọ naa gun ọkada alawọ buluu lọjọ naa lo mu ko lọọ ko sẹnu ọkọ tipa to n bọ jẹjẹẹ rẹ, ti iyẹn si tẹ ẹ pa loju-ẹsẹ.

Ohun ta a gbọ ni pe gbogbo igbiyanju awakọ tipa ọhun lati ya fun un lo ja si pabo pẹlu bi bireeki ọkọ rẹ ṣe daṣẹ silẹ, ti ko si mu un mọ nigba to fẹẹ duro lojiji ko ma baa a kọ lu ọlọkada naa.

Awakọ tipa ọhun ko rin ju bii opo-ina meji to fi duro, ti oun ati ọmọọṣẹ rẹ si bẹ jade kuro ninu ọkọ naa, ti wọn si sa lọ tefe tefe nitori ibẹru itu tawọn eeyan le fi wọn pa.

Awọn oluworan kan ni wọn fi kẹkẹ Maruwa gbe oku ọmọkunrin naa kuro nibi to ku si laarin titi, ti wọn si lọọ tọju rẹ si mọṣuari ọsibitu ijọba to wa niluu Ondo, ki wọn too ṣẹṣẹ lọọ fi iṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa Ẹnu-Ọwá leti.

 

Leave a Reply