Eyi lawọn ti ẹgbẹ APC fọwọ si pe wọn kunju oṣuwọn lati dupo gomina l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Igbimọ ti ẹgbẹ All Progressive Congress lorilẹ-ede yii gbe kalẹ lati ṣe ayẹwo fawọn to fẹẹ dije ninu eto idibo gomina to n bọ lọna nipinlẹ Ondo, ninu oṣu Kọkanla, ọdun 2024 yii, ti ni gbogbo awọn oludije ti wọn gba fọọmu ni wọn kunju oṣuwọn lati dije lẹyin ayẹwo ti awọn ṣe fun wọn.

Gomina ipinlẹ Ondo, Ọnarebu Lucky Ayedatiwa, wa lara awọn oludije ẹgbẹ APC ti igbimọ ọhun, eyi ti Ọjọgbọn Abdulkarim Kana, jẹ alaga rẹ buwọ lu pe wọn yege lati kopa ninu eto idibo abẹle ẹgbẹ APC ti yoo waye l’ogunjọ, oṣu Kẹrin, ọdun yii.

Ọjọgbọn Kana sọ ninu atẹjade to fi sita pe ko soootọ ninu ẹsun ti ọkan ninu awọn oludije, iyẹn Olugbenga Ẹdẹma, fi kan Ayedatiwa pe ayederu ni iwe-ẹri oniwee mẹwaa lo fẹẹ fi dije dupo gomina.

O ni awọn ti ṣe iwadii ẹsun yii daadaa lori ikanni ajọ Wayẹẹki funra wọn, nibi ti awọn ti fidi rẹ mulẹ daju saka pe loootọ ni Ayedatiwa kẹkọọ jade nile-iwe girama Ikosi High School, to wa niluu Eko.

Alaga igbimọ ọhun waa kilọ fun gbogbo awọn oludije labẹ asia ẹgbẹ APC lati kiyesara, ki wọn si yago fun fifi awọn ẹsun ti ko lẹsẹ nilẹ kan ara wọn lori erongba ati tabuku tabi ba oludije kan jẹ loju araalu.

O ni gbogbo awọn to gba fọọmu labẹ ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress lawọn ṣe ayẹwo fun daadaa ki awọn too buwọ lu wọn gẹgẹ bii ẹni to yẹ lati kopa ninu eto idibo abẹle to n bọ lọna.

Awọn ti igbimọ ọhun buwọ lu orukọ wọn ni: Gomina Lucky Ayedatiwa,  Ifẹoluwa Oyedele, Isaac Kekemeke, Jimi Odimayọ, Jimoh Ibrahim,  Sọji Ẹhinlanwo, Wale Akintẹrinwa, Oluṣọla Oke, Olugbenga Ẹdẹma, Mayọwa Akinfọlarin, Felix Okunlẹyẹ, Diran Iyantan, Dayọ Faduyile, Morayọ Lẹbi ati Abilekọ Funmilayọ Waheed Adekojọ.

Leave a Reply