Oluwoo we lawani fun Imaamu Agba tuntun niluu Iwo

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Oluwoo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi, ti we lawani fun Muhammed -Thanni AbdulMumin Adedeji, gẹgẹ bii Imaamu agba ilu Iwo.

Ninu aafin ori-ade yii ni ayẹyẹ iwelawani naa ti waye lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹrin, ọdun yii.

Tẹ o ba gbagbe, ọsẹ to kọja ni Imaamu agba ilu naa tẹlẹ, Sheik Abdulfatah Olododo, jade laye, bẹẹ naa si ni ẹni to jẹ Ọtun Imaamu, Sheik Muhammed Ẹjalonibu naa ku loṣu meji sẹyin.

Idi niyi ti ipo naa fi kan Thanni-Muhammed Adedeji, lati jẹ Imaamu agba ilu Iwo, ti wọn si tun yan Sheik Fatai Tẹlla to jẹ ẹkẹta Imaamu si ipo Ọtun Imaamu.

Ki Ọba Akanbi too we lawani fun Imaamu agba yii lo ti sọ ọ di mimọ pe ilu Iwo nikan ni ọba ti maa n fi Imaamu agba jẹ nilẹ Yoruba.

O ni aṣa ilu Iwo yatọ gedegbe, Oluwoo ko gbọdọ gbe ẹsin miiran leke yatọ si ẹsin Islaamu, o si gbọdọ maa fọnrere ẹsin naa lojoojumọ.

Ọba Akanbi rọ Imaamu tuntun naa lati di opo ẹsin Islaamu mu daradara, ko gbọdọ faaye gba ibọriṣa, bẹẹ ni ko si gbọdọ faaye gba ẹsin ajeji miiran.

O ni lẹyin ti awọn igbimọ Shura ti fori kori lati yan awọn eeyan ọhun loun naa fi ọwọ si i, ti oun si we lawani fun wọn nibaamu pẹlu aṣa ilu Iwo.

Bakan naa lo rọ gbogbo awọn Musulumi niluu naa lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn adari tuntun naa, ki ilu Iwo le tubọ maa jẹ awọkọṣe rere kaakiri ilẹ Yoruba.

Ọmọ agboole Akinlẹwa, ni Mọlete Quarters, niluu Iwo, ni Imaamu Adedeji, o kẹkọọ gboye ninu ẹsin Islam (Islamic Studies) ni Fasiti Ilọrin ati Al-Hikma University, Ilorin, nipinlẹ Kwara.

Leave a Reply