Adewale Adeoye
Beeyan ba jẹ ori ahun to ba ri bi awọn oṣiṣẹ ajọ ẹṣọ oju popo, ‘Federal Road Safety Corps’ (FRSC), ẹka tipinlẹ Kano, ṣe n fa oku awọn araalu kan yọ ninu mọto to lasidẹnt lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii, aanu aa ṣeeyan.
Iṣẹlẹ ibanujẹ ọhun waye lagbegbe Gaya Junction, nipinlẹ Kano, laarin mọto akero meji kan iyẹn Toyota Hiace, ti nọmba rẹ jẹ KTG 190 XB, ati mọtọ Hijet kan ti nọmba rẹ jẹ KTG 501 YG.
ALAROYE gbọ pe ere asapajude tawọn dẹrẹba mọto akero ọhun n sa lọjọ naa lo ṣokunfa iṣẹlẹ ọhun. Ero mẹrinlelogun kan ti ori ko yọ lọwọ iku ojiji lasiko ijamba ọkọ naa ni wọn wa lẹsẹ-kan-aye, ẹsẹ-kan-ọrun nileewosan ijọba agbegbe naa ti wọn n gba itọju lọwọ bayii, nigba tawọn mejila ku loju-ẹsẹ sinu iṣẹlẹ ọhun.
Ijamba ọkọ ọhun lo mu ki ọga agba ajọ to n ri igbokegbodo ọkọ loju popo (FRSC) ẹka tipinlẹ Kano, Ọgbẹni Dauda Biu, fi fajuro si bawọn dẹrẹba mọto akero ṣe n sare asapajude lasiko ti wọn n ba rin irin-ajo, ati bi wọn ṣe n lo taya aloku si ẹsẹ mọto wọn.
Atẹjade kan ti wọn fi sita lọjọ Ẹti, Furaidee, ogunjọ, oṣu yii, iṣẹlẹ ọhun lo bayii pe, ‘O yẹ kawọn dẹrẹba maa ṣọra gidi, paapaa ju lọ lasiko ti wọn ba n wa ọkọ loju popo, wọn ko gbọdọ sare ju loju titi bẹẹ ni ki wọn yee ra taya aloku si ẹsẹ mọto wọn mọ. Ẹmi ko laarọ.
Ọga agba ajọ FRSC ni iwadii tawọn ṣe nipa iṣẹlẹ ọhun fi han pe ere asapajude tawọn dẹrẹba ọkọ naa n sa lọjọ yii lo ṣokunfa iṣẹlẹ to mu ọpọ ẹmi eeyan lọ yii.
O gba awọn awakọ lamọran pe ki wọn ri i daju pe gbogbo ẹya ara mọto wọn lo n ṣiṣẹ daadaa ko too di pe wọn gbe e sọna.