Awọn iṣẹlẹ kan ki i ye eeyan to ba ṣẹlẹ, eeyan yoo kan maa wo o pe ki lo de tiru eyi fi gbọdọ waye rara ni. Ṣugbọn to ba ṣẹlẹ, ko sohun teeyan yoo ṣe si i ju ka ba wọn daro naa lọ. Iru ẹ ni iṣẹlẹ yii, to jẹ mọto gba ọkọ, o gba iyawo to wa ninu oyun oṣu mẹsan-an, o si pa awọn mejeeji soju kan naa nipinlẹ Delta!
Kingsley Akpor lorukọ ọkọ, Ajọkẹ lorukọ iyawo. Iṣẹ to ni i ṣe pẹlu aworan yiya lọkọ n ṣe, wọn si n gbe igbesi aye alaafia lẹyin igbeyawo wọn ti wọn ṣe loṣu marun-un sẹyin.
Ibi ayẹyẹ ọjọọbi kan ti wọn ṣe ni PTI Conference Center, ni Delta, ni wọn ti n bọ lọjọ keji, oṣu karun-un, ọdun 2021 yii, ti ijamba fi ṣẹlẹ. Wọn fẹẹ sọda titi ni, ni mọto buruku kan ba n sare bọ, o si gba tọkọ-taya Akpor danu, bẹẹ lo ba tiẹ lọ, ko duro rara.
Ninu ọsẹ ti mọto gba awọn mejeeji yii ni awọn dokita sọ pe Ajọkẹ to loyun oṣu mẹsan-an yoo bimọ, gẹrugẹru gbaa lọmọbinrin arẹwa naa wa. Ṣugbọn bi mọto naa ṣe gba wọn ni Ajọkẹ ku toyun-toyun, ti ọkọ rẹ, Kingsley, naa si jẹpe Ọlọrun.
Orin ki leeyan yoo kọ si odidi idile to ṣe bẹẹ parẹ soju titi yii, ko si o, afi ero ya waa wo o naa ni. Awọn eeyan pe pitimu sibẹ, wọn n sunkun kikoro, awọn to si le gbe awọn oku naa ba wọn gbe e, o di mọṣuari.
N ni idile ọkọ atiyawo ba padanu nla, titi dasiko yii loju wọn ṣi n ṣomi gbere, nitori iṣẹlẹ yii wuwo lọkan pupọ, o buru jọjọ.