Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ọkan pataki lara awọn agba oṣere tiata ilẹ wa nni, Ọgbẹni Ganiyu Oyeyẹmi Akinpẹlu, ẹni ti gbogbo eeyan mọ si Ogunjinmi Ajagajigi oogun, ti jade laye.
Ẹni ọdun mẹrindinlaaadọrin ni ọkunrin naa ko too dagbere faye laaarọ ọjọ Ẹtim Furaide, ọsẹ yii, iyẹn ọjọ kẹrinledinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun yii.
Oṣere kan, Kunle Afod, lo kọkọ fi ikede naa sita nipa iku oloogbe yii.
Alaroye gbọ pe wọn ti sinku baba naa nile rẹ to wa lagbegbe Owoẹba, loju ọna Oṣogbo si Ileṣa.
Akọbi oṣere naa, Ismaila Oyeyẹmi Akinpẹlu, ṣalaye pe laarin aawẹ awọn Musulumi ni aisan to pada yọri si iku yii bẹrẹ si i ṣe agba oṣere naa.
O ni awọn ko si wo baba naa niran rara, kia lawọn gbe e lọ si ọsibitu, nibi to ti n gba itọju ko too di pe o dakẹ si ọsibitu kan lagbegbe Kọla Balogun, niluu Oṣogbo.
Ismaila ṣapejuwe baba rẹ gẹgẹ bii ẹni to ko tọmọde-tagba mọra, o ni ko sẹni to le ba ẹkun de ọdọ rẹ ti ko nii rẹrin jade.