Agbọ-sọgba-nu ni iroyin iku Pasitọ Dare Adeboye, ọkan ninu awọn ọmọ Pasitọ ijọ Ridiimu, Enock Adeboye, jẹ fun gbogbo awọn eeyan, paapaa awọn ọmọ ijọ naa.
Idi ni pe ọkunrin naa ko saisan ti tẹlẹ, wọn ni niṣe ni pasitọ ẹni ọdun mejilelogoji naa to jẹ oluṣọagutan ijọ Ridiimu to wa niluu Eket, nipinlẹ Akwa Ibom, sun ti ko si ji mọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.
ALAROYE gbọ pe ko si nnkan kan to ṣe pasitọ naa, wọn ni o pa foonu rẹ, o ni oun ko fẹ ki ẹnikẹni yọ oun lẹnu, oun fẹẹ sun, bẹẹ lo si lọọ sun.
Ṣugbọn nigba ti iyawo rẹ, Temiloluwa Adeboye, ṣakiyesi pe ọkọ oun ti sun tipẹ, ti ki i si i sun bẹẹ tẹlẹ lo pe foonu rẹ, nigba to pe foonu yii ti ko gbọ ijẹ kankan latọdọ rẹ, to si gba ilẹkun yara naa ti ko sẹni to daa loun lo mu ariwo bọnu.
O ṣe ni laaanu pe nigba ti wọn pada ṣilẹkun yara naa, oku Pasitọ Dare Adeboye ni wọn ba, ọkunrin naa ti ku.
Awọn ojiṣẹ Olọrun ijọ naa kora wọn jọ lati gbadura boya ọkunrin yii le ji saye, ṣugbọn ọrọ ko ri bẹẹ mọ.
Adari eto iroyin fun ijọ Ridiimu, Pasitọ Ọlaitan Olubiyi, fidi iroyin iku ọkan ninu awọn ọmọ olori ijọ Ridiimu naa mulẹ, o ni loootọ ni Pasitọ Dare ti ku ni Eket, nipinlẹ Akwa Ibom, to n gbe, ṣugbọn ohun ko ti i le ṣalaye ohunkohun nipa iku rẹ.
Ti ki i baa ṣe iku to pa oju rẹ de yii, inu oṣu to n bọ, iyẹn oṣu kẹfa, ọdun yii, ni Pasitọ Dare to jọ Baba Adeboye bii imumu iba pe ẹni ọdun mẹtalelogun laye.
Ọkunrin yii ni akọbi Pasitọ Adeboye lọkunrin, ọmọ iyanu ni baba naa si maa n pe e.
Ni ọdun to kọja ti Pasitọ Adeboye ki ọmọ rẹ yii ku oriire lo sọ pe Ọlọrun dojuti satani nigba ti awọn bi ọmọkunrin awọn yii.
O kọ ọ pe ‘Ọmọ iyanu wa akọkọ, a gbadura pe Ọlọrun yoo tẹsiwaju ninu iṣẹ iyanu rẹ ninu aye rẹ ati ninu aye gbogbo awọn ti wọn nilo iyanu lonii. A lo ọ gẹgẹ bii ohun eelo afọwọkan fun aye tiwọn naa lorukọ Jesu. Ọrọ ifẹ yii wa lati ọdọ baba, mama ati gbogbo mọlẹbi Adeboye lapapọ.’
Bi baba yii ṣe kọ ọrọ ikinni si ọmọ rẹ ti wọn ni o jẹ ọkan ninu awọn pasitọ to maa n waasu fun awọn ọdọ ti awọn eeyan si fẹran daadaa ọhun ree lasiko ọjọ ibi rẹ lọdun to kọja. Ṣugbọn o ṣe ni laaanu pe iku ko jẹ ki o ṣe ọjọ ibi mi-in loke eepẹ.
Ọpọ awọn to ti gbọ nipa iṣẹlẹ buruku naa ni wọn n ba mọlẹbi Adeboye kẹdun, ti wọn si n gbadura pe ki Ọlọrun tu wọn ninu.