O ma ṣe o! Wọn fipa ba akẹkọọ Fasiti Ilọrin lo pọ titi to fi ku ni Kwara

Ibrahim Alagunmu, Ilorin

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni awọn janduku kan fi tipa ba Ọlajide Ọmọwumi Blessing to jẹ akẹkọọ Fasiti Ilọrin ni ẹka imọ nipa eto ọgbin lo pọ, ti wọn si tun ṣeku pa a lẹyin ti wọn ba a lo pọ tan.

Blessing lo jẹ ọmọ bibi ilu Oke Ọpin, nijọba ibilẹ Ekiti, nipinlẹ Kwara, ṣugbọn to n gbe pẹlu aunti rẹ ni agbegbe Tankẹ, niluu Ilọrin, nibi to sun mọ, ọgba ile ẹkọ Fasiti Ilọrin to n lọ.

ALAROYE gbọ pe Aunti Blessing ti wọn jọ n gbele jade lọ si ẹnu iṣẹ rẹ ni ọjọ buruku ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ni, nigba to dari ibi iṣẹ de ni nnkan bii aago mẹfa irọlẹ lo ba ilẹkun ni titi pa. O kan ilẹkun, ko gbọ ijẹ, o pe ago Blessing, ko gbe e, lo ba ke si awọn araadugbo, ni wọn ba ja ilẹkun wọle. Si iyalẹnu wọn, oku Blessing ni wọn ba nilẹẹlẹ nihooho ọmọluabi, wọn de e lokun lọwọ sẹyin, bakan naa ni wọn ti ṣe oju ara rẹ basubasu, wọn tun fi beba kekere kan di i lẹnu pẹlu.

Iwadii fi han pe lẹyin ti wọn ṣeku pa a tan, wọn kọ iwe kalẹ, ohun ti wọn kọ ni pe, “ ko si idariji ni Unilọrin.’’

Wọn fi iṣẹlẹ naa to agọ ọlọpaa to wa ni (F Division) leti, ti wọn si lọ sibẹ lati lọọ wo ohun to ṣẹlẹ. Wọn ti gbe oku oloogbe naa lọ si ile iwosan Fasiti Ilọrin (UITH) fun ayẹwo to peye.

Kọmisanna ọlọpaa ni ipinlẹ Kwara, Mohammed Bagega ti koro oju si iṣẹlẹ naa, o si ni ki wọn ṣe iwadii to gbopọn lori iṣẹlẹ naa, ki wọn si fi oju awọn aṣebi han.

 

Aṣofin to n ṣoju ẹkun idibo Ekiti Oke Ẹrọ, Họnọrebu Ganiyu Abọlarin, naa ti bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ ọhun, to si ni ki awọn ẹsọ alaabo gbe igbesẹ akin lati fi awọn ti aje iwa ibajẹ naa ba ṣi mọ lori jofin.

Leave a Reply