O ti ṣẹlẹ, awọn ẹgbẹ Ajẹ lorileede Naijiria kilọ fun Ọṣinbajo, wọn ni ko ma dupo aarẹ

Saka Monisọla

Ẹgbẹ awọn Ajẹ funfun ni orilẹ-ede Naijiria ti kilọ fun Igbakeji Aarẹ ilẹ wa, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, lati ma ṣe dije dupo Aarẹ ọdun 2023 to n bọ lọna.

Awọn ẹgbẹ Ajẹ yii ni wọn jade pẹlu iṣipaya pe Ọṣinbajo ko le gbegba oroke ninu eto idibo Aarẹ to n bọ lọna, bo ti wu ko gbiyanju to.

Awọn ẹgbẹ yii sọ pe iṣẹ pataki ni Ọlọrun ran Ọṣinbajo, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun 2023, ni yoo pari iṣẹ ọhun, ati pe ni kete to ba ti pari, niṣe ni ko pada sidii pẹpẹ, nibi ti Ọlọrun ti ni iṣẹ pataki to ju ki o jẹ olori orile-ede lọ fun un.

Agbẹnusọ wọn to tun jẹ ọkan ninu awọn igbimọ, ẹgbẹ ọhun nipinlẹ Edo, Dokita Iboi Okhue, sọ pe Ọlọrun lo ran Igbakeji Aarẹ niṣẹ kan pato, o waa gba a nimọran pe ifowo, agbara ati akoko ṣofo ni ti Ọjọgbọn nipa imọ ofin naa ba taku pe oun fẹẹ di Aarẹ lẹyin Muhammadu Buhari.

Okhue ni lẹyin ipade awọn Ajẹ ti wọn ṣe ni Aladija, Warri, nipinlẹ Delta, ninu oṣu Keji, ọdun yii, oriṣiiriṣii ọrọ ni wọn gbe yẹwo, ninu eyi ti wọn ti sọ nipa eto idibo ti wọn ni yoo lọ ni irọwọrọsẹ lọdun to n bọ leyii, to fi jẹ pe ẹnikẹni to ba jawe olubori gẹgẹ bii Aarẹ, awọn eeyan ilẹ Naijiria yoo gba a gẹgẹ bii olori wọn.

Agbẹnusọ awọn Ajẹ ti ko fẹẹ sọ apa ibi ti aarẹ tuntun yoo ti jẹ nitori eto aabo sọ pe “yoo jẹ ẹni ti awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria yoo fẹran, ti wọn yoo si gba a tọwọ-tẹsẹ. Yoo tun ilẹ Naijiria ṣe fun igbega lẹẹkan si i, yoo si san gbogbo awọn gbese ti Naijiria ti jẹ kalẹ.

‘‘Ọlọrun ran an lati jiṣẹ fawọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria. O ti ṣe iyẹn, ki o pada si ṣọọṣi lo ku. Ọlọrun yoo lo o ni ọna ti o ju ki o jẹ olori orilẹ-ede lọ.” Okhue ṣalaye.

Leave a Reply