Wọn lu baba arugbo pa nitori ọrọ ilẹ, wọn ju oku ẹ seti odo l’Abẹokuta

Gbenga Amos, Abeokuta

 Baba arugbo, ẹni ọdun marundinlaaadọrun-un  (85) kan, Jimọh Ọladiran, ti kagbako iku ojiji, wọn lawọn mọlẹbi rẹ kan tinu n bi ni wọn tan an jade nile rẹ l’Abẹokuta, lọjọ Satide to kọja lọhun-un, atigba naa ni wọn ti n wa a, ki wọn too ri oku rẹ leti odo abule Aṣipa.

Ba a ṣe gbọ, adugbo Ṣomọrin, Alagbọn-mẹta, lagbegbe Ọbantoko, niluu Abẹokuta, ni baba agba yii n gbe, wọn ni baba naa ni oko si Abule Aṣipa, to wa lagbegbe Ọpẹji, nijọba ibilẹ Ọdẹda, ipinlẹ Ogun, ṣugbọn awọn alaamulegbe baba naa ni o pẹ ti Jimọ ti lọ soko rẹ ọhun gbẹyin, tori ọjọ ogbo.

Wọn lawọn mọlẹbi rẹ meji kan, Aafaa Mufatiu ati ọmọ rẹ, Ibrahim Mufatiu ni wọn ṣabẹwo si baba arugbo naa ni Satide, ọjọ kejila, oṣu Kẹta yii, lẹyin ti wọn si ti sọrọ ninu yara, wọn gbe baba naa sinu ọkọ ayọkẹlẹ ti wọn gbe wa, wọn lawọn fẹẹ de oko wọn l’Aṣipa.

Nigba to dọjọ keji, ọjọ Sannde, awọn ọmọ baba naa bẹrẹ si i wa baba wọn, wọn ti lọ si Abule Aṣipa ti wọn dagbere, ṣugbọn wọn ko ri i, wọn o si ri awọn mejeeji ti wọn waa mu baba naa kuro nile rẹ.

Nigba ti wọn dele Aafaa Mufatiu, iyawo rẹ ti wọn ba sọ pe abule mi-in ni wọn lọ.

Akọbi baba arugbo yii, Ọgbẹni Sulaiman Ọladiran, sọ fun ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa pe: “Baba mi pe mi ni nnkan bii aago mẹwaa aarọ Satide, wọn sọ fun mi pe awọn ati mọlẹbi awọn kan ta a ti mọ tipẹtipẹ, Aafaa Mufa, n lọ sabule Aṣipa, wọn lawọn ni eto kan tawọn n lọọ ṣe lọhun-un. Titi tilẹ ọjọ naa si fi ṣu, a o ri wọn.

“Mo pe bọọda wa, to jẹ Baalẹ Aṣipa, Oloye Kẹhinde Omirinde, mo sọ fun wọn nipa ẹ, wọn si ni ki n jẹ kilẹ ọjọ keji mọ, ka too le bẹrẹ si i wa wọn. Nigba to di aago mejila ọsan ọjọ Sannde ti a ko foju kan wọn, ti nọmba foonu wọn ati ti Aafa Mufa ko lọ, mo tun pe Baalẹ Aṣipa, wọn si sọ fun mi pe iduro o si mọ o, ka tete bẹrẹ si i wa wọn, la ba gbera, o di abule Aṣipa.

“A ba iyawo Aafaa Mufa labule naa, nigba ta a beere baba agba lọwọ ẹ, o ni wọn lọ sabule keji, o ni wọn o ni i pẹ ẹ de, ka fọkan balẹ, ko sewu. Ṣugbọn a ri i pe ara ẹ o lelẹ bo ṣe n ba wa sọrọ, irisi oju ẹ ko si ba nnkan to n sọ fun wa mu, ara fu mi, mo mọ pe afaimọ ni aburu kan o ti ṣẹlẹ.

“Mo pe awọn aburo mi meji ta a jọ n lọ si kọrọ kan, mo sọ ifura ati akiyesi mi fun wọn, awọn naa sọ bakan naa pe ara n fu awọn si iyawo Aafaa yii.

“Nigba to di irọlẹ ọjọ naa, a ri Aafaa Mufatiu to n bọ lati odo, a bi i leere pe baba wa n kọ, o ni ka mu suuru, ka ṣe suuru. Nigba to ya, o ni ka ṣe oun jẹẹjẹ, tabi ka pa oun ni o. A sọ fun un pe baba wa lawa fẹẹ ri, ki lo ṣẹlẹ, ojiji lo ki ere mọlẹ, lo ba n sa lọ, lawa naa ba gba fi ya a, a le e lọ, ṣugbọn a o ba a.

“Lasiko yii, ọrọ naa ti n ta sawọn ara abule naa leti diẹdiẹ, ohun to ya wa lẹnu ni bawọn gende kan ṣe fa igi ati ada yọ, ti wọn si fẹẹ kọ lu wa, meji ninu wa sa, ṣugbọn wọn mu ẹkẹta wa.

Bi a ṣe sare gbe ọkada wa, ta a kọri sọna Abẹokuta lati lọọ fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa, a pade awọn ọlọpaa OP-MESA ni Ọpẹji, a da wọn duro ninu ọkọ wọn, a ṣalaye nnkan to ṣẹlẹ fun wọn, ni wọn ba ni ka niṣo nibẹ, wọn si ba wa pada sabule Aṣipa, nigba ta a fi maa de’bẹ, wọn ti lu ẹkẹta wa, Kazeem, nilukulu, wọn ṣe e lẹṣe gidi.

“Ṣa, awọn ọlọpaa OP-MESA yii mu Aafaa Mufatiu, wọn fa a le awọn ọlọpaa teṣan Bode Olude lọwọ, wọn ni ka pada wa lọjọ keji. Nigba ta a pada debẹ lọjọ keji, ọjọ Mọnde, awa ati awọn ọlọpaa la tẹle Aafaa Mufa, o loun n mu wa lọ ibi ti baba wa wa, o dori kọ eti odo kan nitosi abule naa, ibẹ ni wọn pa a si. A ri ipa ẹjẹ lori ẹni ti wọn lo sun ni, a si ri apa bi wọn ṣe lu nnkan mọ ọn lori, wọn fi aṣọ kan ti ẹjẹ rin gbingbin we e leti omi nibẹ, oku rẹ si ti n run, o ti n jẹra.

“Baalẹ abule naa, Oloye Omirinde, ṣalaye fun wa pe nigba kan, baba wa to doloogbe yii sọ foun pe ki oun pin ilẹ fun Aafaa Mufatiu ati ọmọ rẹ, o ni wọn n da oun laamu pe awọn fẹẹ gba ogun, awọn si nilo ilẹ. Ṣugbọn baalẹ naa loun o da oloogbe lohun, tori oun o mọ awọn to ni koun fun nilẹ yii ri, oun o si mọ wọn mọ mọlẹbi kankan labule naa,” bẹẹ ni Sulaiman sọ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o ni Aafaa Mufatiu ati ọmọ rẹ ti wa lakolo awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ, ti wọn n ṣewadii iwa ọdaran bii eyi.

O lawọn maa tuṣu desalẹ ikoko lori ọrọ naa, awọn si maa jẹ ki idajọ ododo waye lori ẹ.

Leave a Reply