Ọbasanjọ gba Buhari nimọran: Ọwọ lile kọ o, lọọ pepade alaafia pẹlu awọn ti wọn fẹẹ ya kuro ni Naijiria  

 Faith Adebọla

Aarẹ ilẹ wa tẹlẹ ri, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, ti ṣekilọ pe afaimọ ki ọrọ awọn eeyan ti wọn n pariwo pe awọn maa ya kuro lorileede Naijiria lọọ da orileede ẹya tiwọn silẹ, afaimọ kọrọ naa ma mu ijọba lomi gidi, o si le kọja ohun ti apa ijọba apapọ yoo ka, pẹlu bi wọn ṣe gun le fifọwọ lile mu ọrọ ọhun.

Ọbasanjọ ni oun ko lodi si ki Aarẹ Muhammadu Buhari ṣepade alaafia pẹlu awọn ajijagbara to n fọnrere iyapa yii, o ni ọna toun mọ to daa ju lọ lati bojuto awuyewuye ọhun niyẹn.

Lasiko to n dahun ibeere tawọn oniroyin ilu eebo kan, tileeṣẹ Newsweek bi i l’Ọjọbọ, Tọsidee yii, lori ipo torileede Naijiria wa, l’Ọbasanjọ sọrọ naa.

Ọbasanjọ ni “Mi o rohun to buru ninu ki Buhari ṣepade pẹlu Nnamdi Kanu, tabi awọn eeyan mi-in ti wọn n sọrọ yiya kuro lara Naijiria, mi o le ta ko iru igbesẹ bẹẹ, kaka bẹẹ, mo maa fun wọn niṣiiri lati ṣe bẹẹ ni.

“To ba jẹ emi ni Aarẹ ni, niṣe ni ma a pe Kanu, ma a tun pe awọn mi-in ti ọrọ wọn jọra pẹlu tiẹ, awọn ẹlẹgbẹ ẹ, ma a si bi wọn leere pe: ‘Ki niṣoro yin gan-an, ki lẹ fẹ’? Ki i ṣe Kanu lati ilẹ Ibo nikan o, mo maa pe awọn ajijagbara to wa lawọn agbegbe mi-in pẹlu.”

Baba naa tun sọ pe bawọn ologun ṣe fẹẹ fọwọ lile mu ọrọ yii lewu, ko le mu ojutuu wa, bẹẹ si lọrọ awọn to fẹẹ ya kuro naa ko le mu ojutuu wa. O ni ọwọ pẹlẹkutu lo yẹ kijọba fi mu ọrọ ọhun, tori iṣoro to le mu Naijiria lomi ni.

“A gbọdọ pese iṣẹ to to fawọn ọdọ wa, iṣẹ gidi, ka si fẹsẹ wọn le ọna ati la, ka pese ọjọ ọla to nitumọ fun wọn, ki ireti wọn fun ọjọ ọla rere le duro. Ko sọna abayọ mi-in.”

Leave a Reply