Ọdaju abiyamọ sọmọ oṣu mẹfa yii nu, awọn alaaanu kan lo ri i he

Faith Adebọla, Eko

Bi ko ba si ti awọn alaaanu kan ti Ọlọrun fi ṣe kongẹ ọmọ oṣu mẹfa kan tiya ẹ ti gbe sọnu ni, ori ẹkun ni iba ku si, ọpẹlọpẹ awọn ti wọn tete doola ẹmi ọmọ naa.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko, CSP Olumuyiwa Adejọbi, sọ f’ALAROYE pe inu ile kan to wa ni 24B, Plot 3006, Opopona Rafiu Babatunde Tinubu, Amuwo Ọdọfin, nipinlẹ Eko, ni wọn ju ọmọ yii sọnu si, wọn si tilẹkun mọ ọn sibẹ, bẹẹ ni ko sẹnikan nitosi fulaati naa.

Awọn aladuugbo ẹlẹyinju aanu kan ni wọn gbọ b’ọmọ naa ṣe n ke lai dakẹ, ni wọn ba pariwo boya iya rẹ wa nitosi, wọn si ri i pe ko sẹnikan to dahun, eyi ni wọn fi yọju sọmọ naa, o si ya wọn lẹnu pe ọmọ jojolo yii nikan ni wọn ba nibẹ.

Wọn ta ileeṣẹ ọlọpaa lolobo, awọn ọlọpaa lati ẹka Festac si tete de ibi iṣẹlẹ naa. Ko kuku sẹni to mọ orukọ ọmọ ọhun, bẹẹ lawọn eeyan ti wọn wa laduugbo naa lawọn o ri oju ọmọ naa ri, awọn ko si le sọ igba ti iya rẹ tabi ẹni yoowu to ju u sibẹ huwa ika ọhun.

Adejọbi ni ileeṣẹ ọlọpaa pẹlu ajọṣepọ awọn oṣiṣẹ ajafẹtọọ ọmọde kan ti gbe ọmọ naa lọ si ibudo ti wọn ti n tọju awọn ọmọ orukan atawọn alailobii, Juvenile and Women Centre, to wa ni Alakara.

Kọmiṣanna ọlọpa Eko, Hakeem Odumosu, ni ijọba yoo bojuto ọmọ naa, wọn si maa pese itọju to yẹ fun un.

Bẹẹ lo parọwa pe kawọn ti wọn ba n daṣa jiju ọmọ nu lọọ jawọ ninu ẹ tori o lodi sofin, ko si bojumu lawujọ wa.

Leave a Reply