Ijọba apapọ yan ipinlẹ Ogun lati janfaani oriṣii mẹta labala ọgbin

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Wọn ti yan ipinlẹ Ogun gẹgẹ bii ilu ti yoo jẹ anfaani ọna mẹta tijọba apapọ n ṣeto labala eto ọgbin ati ipesẹ ounjẹ.

Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ karun-un, oṣu karun-un yii, ni akọwe to n ri si iṣẹ ọgbin lẹka ijọba apapọ, ‘NALDA’(National Agricultural Land Development  Authority) Ọgbẹni Paul Ikonne, sọ eyi di mimọ lọfisii Gomina Dapọ Abiọdun, l’Oke-Mosan.

O ni eto mẹta ti wọn darukọ ipinlẹ Ogun fun naa ni Ẹsiteeti ọgbin rẹpẹtẹ, aaye ti wọn ti n ṣe gaari ati kikọ awọn akẹkọọ jade igba (200) lẹkọ lori ilẹ ọgbin. Awọn to ba kẹkọọ yii yoo lanfaani ati maa ri ounjẹ oojọ wọn pẹlu iṣẹ ti wọn ba n ṣe.

Ẹkun mẹtẹẹta ti ipinlẹ Ogun pin si, iyẹn Abẹokuta, Ijẹbu ati Yewa ni Akọwe NALDA sọ pe ijọba apapọ yoo gbe ẹsiteeti oko nla naa si, o ni wọn ki yoo si da iṣẹ ibẹ da awọn eeyan, lati ibẹrẹ ọgbin titi dori gbigbe awọn ere oko lọ sọja lo ni ijọba apapọ yoo lọwọ si.

Bakan naa lo ni sare ilẹ ẹẹdẹgbẹrin (700 hectares) to wa ni Jọga Orile, yoo gba agbara ijọba laipẹ, o ni igbedide ilẹ naa yoo mu kounjẹ tun pọ si i nipinlẹ Ogun ni.

Nigba to n fesi, Gomina Dapọ Abiọdun sọ pe koko kan pataki ni iṣẹ agbẹ ninu iṣẹjọba oun, o loun ko fọwọ yẹpẹre mu un rara. O ni nitori ẹ loun ṣe bẹrẹ papakọ ofurufu akẹru ti yoo ran iṣẹ ọgbin lọwọ. O waa dupẹ lọwọ Aarẹ Buhari fun atilẹyin rẹ, o ni idasi ijọba apapọ labala ọgbin ko ṣee fọwọ rọ sẹyin ninu ijọba oun.

Leave a Reply