Ọdẹ adugbo yinbọn pa mẹkaniiki, wọn tun ji owo ẹ lọ l’Oṣogbo

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọmọkunrin atọkọṣe kan, Mohammed Badmus, ẹni ogoji ọdun, ni ọdẹ adugbo Ibuowo Estate, niluu Ọkinni, nipinlẹ Ọṣun, ti yinbọn pa bayii.

Alajọgbele Mohammed, Hammed Ọparinde, ṣalaye pe ẹgbẹrun lọna ọọdunrun un Naira to wa lapo oloogbe naa to fẹẹ fi ba onibaara rẹ ra ẹnijinni ọkọ tuntun tun dawati lapo rẹ.

A gbọ pe ibi ariya ọjọọbi kan ni Mohamned ti n bọ lalẹ patapata lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, orita to si ja silee rẹ lo ti ṣalabaapade awọn ọlọdẹ naa.

Bi wọn ṣe da a duro lo ṣalaye ara rẹ pe ile oun lo wa lọọọkan yẹn, ṣugbọn pẹtẹpẹtẹ ada la gbọ pe awọn ọlọdẹ naa fi tẹle e denu ile, wọn duro niwaju ita, ọmọkunrin naa si gba ẹyinkule ṣilẹkun iwajuuta lati le fidi rẹ mulẹ fun wọn pe ile ti oun n gbe ni.

A gbọ pe bo ṣe ṣilẹkun iwaju ile ni ọkan lara awọn ọdẹ naa yinbọn fun un lookan aya, to si ṣubu lulẹ loju-ẹsẹ. A gbọ pe wọn ko ba owo ẹnjinni to fẹẹ lọọ ra bi ilẹ ba mọ lapo rẹ.

Ọparinde fi kun ọrọ rẹ pe foonu rẹ nikan ni wọn ri, ko sẹni to mọ bi owo apo rẹ ṣe ra. O ni wọn ti gbe oku rẹ lọ sile igbokuu-si UNIOSUN Teaching Hospital, niluu Oṣogbo.

O ni Mohammed niyawo, o si bimọ mẹta, akọbi ọmọ rẹ ko si le ju bii ọmọ ọdun marun-un lọ.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, Alukooro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, ṣalaye pe ọwọ ti tẹ ọlọdẹ to yinbọn naa, Moshood Rasaq, awọn si ti gba ibọn to yin ọhun lọwọ ẹ.

O ni ẹka to n ṣewadii iwa ọdaran ti ibẹrẹ iwadii lori rẹ lẹyin ti alaga adugbo naa, Olumide Babatunde, ti fi to awọn ọlọpaa leti.

Leave a Reply