Ọga ọlọpaa patapata paṣẹ eto aabo to rinlẹ kaakiri awọn ileewe 

Monisọla Saka, Eko

Lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ni Ọga ọlọpaa patapata lorilẹ-ede yii, Usman Baba, paṣẹ pe ki wọn ko awọn ẹṣọ alaabo lọ sawọn ileewe, ileewosan atawọn ileeṣẹ ijọba jake-jado orilẹ-ede yii fun eto aabo to gbopọn.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ Naijiria, Olumuyiwa Adejọbi, lọ sọ eleyii di mimọ ninu atẹjade to fi lede niluu Abuja lọjọ Aiku.

Baba tun paṣẹ pe ki awọn agbofinro maa wọde kaakiri igboro, ki wọn maa ṣe duro-n-yẹ-ọ-wo fawọn mọto loju popo, ki wọn si tun maa wa ibi kọlọfin awọn aṣebajẹ loorekoore lati le mu adinku ba iwa ibajẹ to ti gogo lawọn ipinlẹ kan lorilẹ-ede yii.

Nigba to n sọ ibi tọrọ eto aabo de duro nilẹ wa pẹlu awọn esi iwadii loriṣiiriṣii tawọn teṣan ọlọpaa ko jọ lo paṣẹ naa.

O waa ke pe awọn ọga lẹnu iṣẹ ọlọpaa kaakiri ipele ati ipo wọn lati mu iwadii ati itọpinpin abẹnu ni ṣiṣe ni Pataki, paapaa ju lọ awọn ọgbọn abẹle lati le mọ ibuba awọn ọdaran, ki wọn le tu wọn sita.

Baba waa rọ awọn ọlọpaa lati ma ṣe figba kankan tura silẹ, ki wọn ma ṣe kaaarẹ ọkan ninu jija ta ko iwa ọdaran, koda ki wọn ma ṣe bẹru lati lọọ kan ilẹkun afurasi ọdaran, titi kan inu igbo atawọn ile akọku ti wọn maa n farapamọ si.

O ni ki wọn maa ṣe akọsilẹ awọn afurasi ọdaran, ki wọn si fi oju awọn to ba yẹ ninu wọn bale-ẹjọ bo ṣe tọ ati bo ṣe yẹ.

Ọga ọlọpaa yii tun rọ awọn eeyan ilẹ Naijiria lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn agbofinro pẹlu bo ṣe jẹ pe laipẹ ọjọ, wọn yoo maa ri awọn ọlọpaa lawọn ibi kọọkan, awọn oju ọna ati lawọn ibi kan ninu ilu. O lawọn da ọgbọn yii lati dena iṣẹ ọwọ awọn ẹni ibi ni.

Baba waa ṣekilọ fawọn ọlọpaa pe, bi wọn ba ran ni niṣẹ ẹru, a maa n fi tọmọ jẹ ẹ ni. O ni ki wọn ṣiṣẹ wọn bii iṣẹ, ki wọn si jẹ ẹ gẹgẹ bii ọmọluabi eeyan. O wa n fọwọsọya pe awọn yoo ri i daju pe awọn ko kuna ninu ojuṣe awọn lati daabo bo ẹmi ati dukia awọn araalu nipa mimu adinku ba awọn iwa ọdaran to jẹ pe awọn ileewe, ile iwosan atawọn ileeṣẹ ijọba ni afojusun wọn.

Leave a Reply