Ogunṣua Mọdakẹkẹ ti waja! 

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ogunṣua ilu Mọdakẹkẹ, Ọba Moses Ọladẹjọ Oyediran, Ajombadi Kẹta, ti darapọ mọ awọn baba nla rẹ.

Ọdun 2018 ni wọn kede baba naa gẹgẹ bii Ogunṣua lẹni ọdun mejilelaaadọrun-un.

Gẹgẹ bi ALAROYE ṣe gbọ, ibẹrẹ ọsẹ yii ni baba naa jade laye, ṣugbọn latari pe wọn ki i tete tufọ ọba ni ko jẹ ki ọrọ naa lu sita titi di irọlẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.

Ẹni ọdun mẹrindinlọgọrun-un ni baba naa kọlọjọ too de.

Leave a Reply