Ogun miliọnu lawọn to ji Jimoh gbe ni Kwara n beere 

Ibrahim Alagunmu, Ilorin

Awọn ajinigbe to ji Aburo Magaji Iyemọja, Jimoh Mujemu, gbe ni agbegbe Mandi Okoolowo, n’Ilọrin nipinlẹ Kwara, ti n beere fun ogun miliọnu (20 million) owo itu silẹ lọwọ mọlẹbi rẹ.

Ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọṣẹ yii, ni awọn janduku ajinigbe ya bo agbegbe Mandi, l’Opopona Okoolowo, ti wọn si bẹrẹ si i yinbọn titi ti wọn fi wọle Magaji Iyemọja, ti wọn si ji Jimoh gbe lọ, ti ẹnikẹni ko si mọ ibi to wa.

Ni bayii, awọn mọlẹbi arakunrin naa sọ pe awọn to ji i gbe ti pe ẹrọ ibanisọrọ awọn, wọn si n beere fun ogun miliọnu naira owo itu silẹ lọwọ awọn.

Ẹgbọn arakunrin ọhun to ba ALAROYE sọrọ ni ọrọ awọn ajinigbe naa ti da iṣoro silẹ ninu ẹbi, tori pe awọn o ti i ri miliọnu kan, debi tawọn yoo ri ogun miliọnu naira ti wọn n beere.

Leave a Reply