Faith Adebọla
Alaaja Salimọt Azeez, iya ọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlogoji kan, Ramon Azeez, ti wọn fibọn da ẹmi ẹ legbodo nibi ija to waye ni Iwo Road, niluu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ, ti sọrọ o. Obinrin naa ni ohun kan ṣoṣo tijọba le ṣe foun lori iku gbigbona, iku airotẹlẹ, tọmọ oun ku ni ki wọn wa awọn to ṣiṣẹ laabi ọhun ri, ki idajọ ododo si waye lori wọn.
Alaaja Azeez fi tẹkun-tomije sọ fawọn oniroyin nile rẹ n’Ibadan pe ko si eyikeyii lara awọn ọmọ oun to n ṣẹgbẹ okunkun, Musulumi ododo ni gbogbo wọn, o ni ṣe lawọn kan mọ-ọn-mọ ran ọmọkunrin naa lọ ajo aremabọ lọsan-an gangan.
Obinrin naa tun sọ pe fidio kan wa lọwọ awọn mọlẹbi to ṣafihan bi awọn aṣaaju ajọ tijọba da silẹ lati maa ṣakoso gareeji, Park Management System, ṣe n sọ pe awọn maa lọọ da ọja Shopping Complex ru, oju awọn to sọrọ naa si han rekete ninu fidio ọhun.
Mama naa ni “O ti pẹ gan-an tawọn ẹgbẹ onimọto ti n lo iwaju ṣọọbu yii fun igbokegbo wọn, koda nigba ti mo gba ṣọọbu sibi, ibẹ ni wọn ti n fa siga wọn, ti wọn aa tun yagbẹ sibẹ, ko too di pe mo tun un ṣe.
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ nigba kan, Adisa Bọlanta, lo da sọrọ naa, oun lo ni ka faaye gba wọn ki wọn maa ṣe tiwọn lẹgbẹẹ kan ẹnu geeti wa, a si gba bẹẹ. Pẹlu ba a ṣe faaye gba wọn naa, ko tẹ wọn lọrun.
Ọmọ mi ti wọn pa yii, Fasiti Leed lo ti jade, akọbi mi ti wọn tun fẹẹ pa, to jẹ ori lo ko o yọ, fasiti ilu oyinbo lo ti gboye jade.
Haa, wọn kan pa ọmọ mi ọmọ ọdun mẹtadinlogoji danu bẹẹ yẹn. Afi kijọba ba mi wa awọn to pa mi lọmọ o. Idajọ ododo ni mo n fẹ, ẹsan gbọdọ ke lori wọn ni, tori mo fẹẹ mọ idi ti wọn fi pa ọmọ mi nigba ti ko si nnkan ti wọn jọ n fa mọra wọn lọwọ.