Bi ibo ti wọn fẹẹ di ni 1964 yii ti n sun mọle, bẹẹ ni wahala n fojoojumọ pọ si i. Ohun kan to daju ni pe ẹgbẹ alajọṣepọ ti wọn n pe ni NNA (Nigerian National Alliance) ti pinnu pe awọn lawọn yoo gbajọba, gbogbo ọna ati agbara ni wọn si n lo lati ri i pe ko si ẹlomiiran to tun sun mọ ile ijọba ju awọn lọ. Nibi meji ni ẹsẹ ẹgbẹ yii ti ranlẹ ju lọ, ilẹ Yoruba ati ilẹ Hausa, nitori awọn ẹgbẹ mejeeji ti wọn n ṣe aṣepọ yii, ẹgbẹ NPC (Northern People Congress) lati ilẹ Hausa ti Sardauna Ahmadu Bello, n ṣe olori fun, ati Ẹgbẹ NNDP (Nigerian National Democratic Party), ẹgbẹ Dẹmọ, ti ilẹ Yoruba, ti Ladoke Akintọla jẹ olori wọn, lawọn ẹgbẹ oṣelu meji ti wọn jọ n ṣe ajọṣepọ yii, wọn kan mu ẹgbẹ keekeeke ti ko lorukọ nilẹ Ibo mọ ọn ni. Ṣugbọn awọn alagbara meji ti wọn wa ninu NNA yii, Akintọla ati Sardauna ni.
Ni ti Sardauna, oun ati awọn eeyan rẹ ko fẹ ki ijọba apapọ bọ lọwọ awọn Hausa ni, ṣugbọn eleyii ko ni i ṣee ṣe bi wọn ko ba ni eeyan gidi kan ati ẹgbẹ oṣelu kan lati ilẹ Yoruba tabi ilẹ Ibo. Ninu Ibo ti wọn di tẹlẹ nigba ti awọn oyinbo ṣi wa ni Naijiria, Oloye Nnamdi Azikiwe pẹlu ẹgbẹ oṣelu rẹ, NCNC (National Council of Nigierian Citizens), lawọn oloṣelu lati ilẹ Hausa yii ri lo nigba naa, ti wọn fi di olori ijọba apapọ. Ẹgbẹ mejeeji lo si jọ n ṣejọba lati 1959 titi di 1964 ti wọn n mura ibo tuntun yii. Ṣugbọn ija ti de laarin wọn, Sardauna ati ẹgbẹ NPC rẹ ko ba NCNC ati Michael Okpara to ti di olori ẹgbe naa tuntun, nigba ti wọn ti gbe olori ijọba Naijiria le Azikiwe lọwọ, ṣe mọ; ẹgbẹ Dẹmọ ti Akintọla da silẹ nilẹ Yoruba lẹyin tiwọn naa ba wọn ja, ẹgbẹ AG (Action Group) ti gbogbo wọn jọ n ṣe tẹlẹ lo ku to n ba ṣe.
Ẹgbẹ NCNC ti wọn jọ n ṣejọba apapọ tẹlẹ naa ti ni awọn ko ba NPC ti Sardauna ṣe mọ, wọn ni AG lawọn yoo maa ba ṣe. AG ati NCNC yii naa si ti da ẹgbẹ alajọṣepọ tiwọn naa silẹ, iyẹn UPGA (United Progressive Grand Allianace), wọn si ti ni ẹgbẹ naa lawọn yoo fi gbajọba kuro lọwọ ẹgbẹ NPC ati awọn Hausa ti wọn n ṣejọba, ọna ti wọn si fi le gbajọba naa ni ki wọn ni ọmọ ẹgbẹ to pọ ju lọ nile-igbimọ aṣofi apapọ, ibo ti wọn yoo si fi yan awọn aṣofin apapọ yii naa ni wọn fẹẹ di nipari ọdun 1964 yii, ohun to jẹ ki ariwo ibo naa pọ, ki wahala naa si le koko ree. Ibo akọkọ ti Naijiria yoo di lẹyin ti awọn oyinbo ti lọ ni, awọn ọmọ Naijiria funra wọn ni wọn n ṣeto ibo naa, oriṣiiriṣii ohun ti ko si yẹ ki ibo mu lọwọ lo pọ ninu ohun to ṣẹlẹ kaakiri Naijiria, nibi meji ti wahala si pọ si ju lọ, ilẹ Yoruba ati ilẹ Hausa yii ni.
Ohun to fa eyi ni pe awọn ti wọn n ṣejọba ni awọn ipinlẹ mejeeji yii, ẹgbẹ NPC nilẹ Hausa, labẹ Sardauna, ati ẹgbẹ Dẹmọ, nilẹ Yoruba, labẹ Akintọla, ti pinnu pe gbogbo ohun to ba gba lawọn yoo fun un, ijọba ko ni i bọ lọwọ awọn. Nidii eyi ni wọn ṣe gbogun nla ti gbogbo awọn alatako wọn, to jẹ ẹni yoowu to ba fẹẹ di wọn lọwọ, ẹwọn lo n lọ, tabi ki wọn dẹ awọn tọọgi si i, bi awọn yẹn ko ba si pa a, wọn yoo lu u debii pe yoo di alaabọ-ara, ko si ni i le jade laarin ọdun kan. Ohun tawọn fẹ niyi, pe gbogbo ẹni to ba fẹẹ di wọn lọwọ, ki wọn wa ibi kan ti i mọ, tabi ki wọn da a jokoo soju kan ti ko fi ni i le jade titi ti ibo ti wọn yoo di naa yoo fi waye. Nibi tọrọ naa le fun awọn UPGA nilẹ Yoruba de lo jẹ ki olori ẹgbẹ alajọṣepọ yii ni oun yoo lọọ ri Ọbafẹmi Awolọwọ to wa lẹwọn ni Calabar, ki oun le fi ẹjọ Akintọla sun un.
Loootọ lo lọọ fẹjọ Akintọla pẹlu awọn ọrẹ rẹ sun, ṣugbọn ọrọ ti kọja bẹẹ, nitori imọran lasan ni Awolọwọ le fun wọn, ko si nnkan mi-in to le ṣe, nigba to jẹ ninu ẹwọn loun wa. Igba ti Okpara yoo fi pada de paapaa, nnkan ti tubọ daru si i nilẹ Yoruba. Ṣe ko too di pe oun lọ si Calabar lọdọ Awolọwọ yii, ilu Ogbomọsọ nikan ni kọọfiu wa, nibi ti wọn ti ṣe ofin isede fun wọn, wọn ni wọn ko fẹ iwọde tabi arinkiri kankan ni gbogbo agbegbe naa titi ibo yoo fi kọja, ki onile gbele ni. Nigba ti awọn eeyan ko ba le jade, bawo ni wọn yoo ṣe le kọpa ninu idibo naa daadaa. Ohun ti wọn ṣe ṣe eleyii ni ki ẹnikẹni ma le jade fun kampeeni, ki wọn si le mu ọta wọn ti wọn ba ti mọ pe ko si lẹyin awọn. Ẹgbẹ UPGA ti kọkọ ni awọn yoo pe ijọba wọn lẹjọ lori ohun ti wọn ṣe yii, ṣugbọn lẹyin ti Okpara ti Calabar de, o sọ fawọn eeyan rẹ pe awọn ko ni i pẹjọ kan mọ, nitori bii ẹni to n fi akoko ṣofo lasan ni.
Ko si le ṣe ko ma sọ bẹẹ, nitori nigba ti yoo fi ti Calabar de yii, wọn ti tun ṣe ofin isede yii ni ilu Ọwọ, Ikarẹ, Ijẹbu-Igbo, wọn si n mura lati fi Ibadan ati Abẹokuta naa kun un. Bi awọn UPGA ba waa fẹẹ lọ sile-ẹjọ, ẹjọ meloo ni wọn yoo pe. Ohun to jẹ ki wọn sinmi ree, ati pe ni gbogbo asiko naa, inu oṣu kejila, 1964 ni, oṣu naa ti da si meji, eyi to tumọ si pe ibo ti wọn fẹẹ di naa ko ju ọjọ mẹẹẹdogun si ọjọ mẹwaa lọ mọ, bi wọn ba si lọ sile-ẹjọ, wọn ko ti i ni i gbọ ẹjọ naa rara ti wọn yoo fi dibo wọn. Bakan naa lawọn oloṣelu ti ki i baa ti i ṣe ọmọ ẹgbẹ Dẹmọ nilẹ Yoruba ko si ninu isinmi, nitori laarin oṣu kejila yii nikan, awọn ti wọn rọ da sitimọle nilẹ Yoruba kaakiri ti le ni ọgọrun-un meji, bẹẹ lawọn ti wọn n ṣa wọn sọgba ẹwọn yii ko ti i duro, ẹni ọwọ ba ti tẹ, wọn ko ni i ro o lẹẹmeji ki wọn too ju u si galagala.
Bakan naa lo n ṣẹlẹ nilẹ Hausa, diẹ lo si ku ki wọn ṣa Joseph Tarka pa si Bukuru, nitosi Jos, nibi ti oun ti lọọ ṣe kampeeni. Tarka yii ni olori ẹgbẹ awọn ọmọ Tiv, ni Benue-Plateau, asiko naa lo si jade pe awọn ko ni i ba awọn Hausa ṣe mọ, nitori awọn ki i ṣe Hausa, Tiv, **Biron ati ẹya mi-in lawọn, awọn ki i ṣe Hausa tabi Fulani rara. N ni wọn ba da ẹgbẹ United Middle Belt Congress (UMBC) silẹ, ati Northern Progressive Front (NPF), awọn ẹgbẹ yii ni wọn fi dara pọ mọ awọn UPGA. Ṣugbọn awọn Sardauna koriira rẹ, wọn n wa gbogbo ọna lati ju u sẹwọn, igba ti wọn ko si tete ri i ju sẹwọn, awọn tọọgi ti wọn n lo nilẹ Hausa mura lati pa a. Ko si isinmi ni Kano naa, nitori Aminu Kano ti ko ba NPC tawọn Sardauna ṣe, ẹgbẹ awọn talakawa lo da silẹ ni Kano, o ni ẹgbẹ naa loun yoo fi gbajọba ilẹ Hausa fawọn talaka, loun naa ba n ba awọn UPGA ṣe.
Asiko to yẹ ki awọn ti wọn n ṣeto idibo gbe orukọ awọn eeyan ti wọn fẹẹ du ipo lọ sile-igbimọ aṣofin jade, wọn ko gbe ti ilẹ Hausa jade, wọn ko o pamọ sibi kan ni. Awọn UPGA fẹjọ sun awọn eleto idibo yii, ṣugbọn wọn ko ṣe kinni kan. Ohun to waa fọ ọrọ loju ni ojooro ti wọn ṣe nidii fọọmu ti awọn ti wọn fẹẹ du ipo lọ sile-igbimọ aṣofin yii n gba. Fọọmu naa ṣe pataki, nitori ẹni ti ko ba gba a tabi to ba gba a, ti ko da a pada ni asiko ti wọn da, ko ni i lanfaani lati kopa ninu idibo naa. Wọn ti ko fọọmu jade fun awọn ti wọn fẹẹ du ipo yii, wọn si ti sọ pe ọjọ kejidinlogun, oṣu kejia, 1964, naa ni gbogbo ẹni to ba gba fọọmu yii gbọdọ da a pada, nitori ọjọ naa ni iforukọsilẹ awọn ondupo yii yoo pin. Iṣoro meji lo waa wa ninu fọọmu yii o, paapaa ni ilẹ Yoruba ati ilẹ Hausa. Akọkọ ni pe, nibomi-in, awọn ti wọn fẹẹ gba fọọmu ko ni i ri i gba, nitori wọn yoo ni ẹni ti fọọmu wa lọwọ rẹ ko ti i de, tabi ki wọn ni ko si nile.
Lọna keji, awọn ti wọn gba fọọmu ko ri i da pada mọ, wọn yoo ni ko si akọwe eto idibo lori ijokoo ni. Ni ilẹ Yoruba, awọn ti ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ Demọ ni eleyii n ṣẹlẹ si, nitori wọọrọwọ lawọn to fẹẹ du ipo ti wọn jẹ ọmọ Dẹmọ n ri fọọmu tiwọn da pada, awọn ọmọ ẹgbẹ UPGA ni wọn ni iṣoro. Ni ilẹ Hausa bakan naa, irọrun lawọn ti wọn jẹ NNA, tabi NPC, tawọn Sardauna fi n gba fọọmu, ti wọn si n da a pada, afi awọn ti wọn ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ wọn nikan. Lojiji ni fọọmu didapada naa pari lọjọ kejidinlogun, oṣu kejila, naa, ọjọ naa si ni awọn ẹgbẹ NNA labẹ Sardauna kede pe awọn ọmọ ile-igbimọ aṣofin apapọ mọkanlelọgọta (61) ni wọn ti wọle ọnapoosi (Unopposed), iyẹn lai ni alatako kankan lati ọdọ awọn o. Awọn Akintọla naa lawọn kan naa ti wọle nilẹ Yoruba. Nibẹ lawọn ẹgbẹ UPGA ti yari, ni wọn ba kede pe afi ki wọn sun ibo naa siwaju o, bi wọn ko ba sun un siwaju, wahala ni!