Ọjọ kẹsan-an, oṣu keje, ni wọn yoo sinku T.B Joshua  

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ẹbi Oloogbe Pasitọ Temitọpẹ Balogun Joshua, ti fi atẹjade sita lori bi isinku oludasilẹ ṣọọṣi Synagogue naa yoo ṣe lọ. Ninu rẹ ni wọn ti kede pe ọjọ kẹsan-an, oṣu keje, ọdun 2021, ni pasitọ agbaye naa yoo wọ kaa ilẹ lọ.

Aya Oloogbe, Evelyn Joshua, lo fi atẹjade naa sita lorukọ igbimọ oludari ṣọọṣi Sinagọgu, bi wọn si ṣe too lẹsẹẹsẹ ree: Ọjọ karun-un, oṣu keje, ni eto isinku yoo bẹrẹ pẹlu titan ina abẹla, ti awọn eeyan yoo maa to lọwọọwọ pẹlu idaro. Aago mẹfa aabọ irọlẹ leto yii yoo bẹrẹ.

Ọjọ kẹfa ni wọn yoo maa sọrọ imọriri Pasitọ T.B Joshua, ti kaluku yoo maa sọ ohun to mọ nipa iṣẹ to gbele aye ṣe. Aago mẹwaa aarọ si meje alẹ ni eyi yoo fi waye

Nigba to ba di ọjọ keje, oṣu keje, ni wọn yoo ṣe isin alẹ orin onigbagbọ ati aṣaalẹ iyin. Aṣemọju leyi, aago mejila oru ni yoo bẹrẹ.

Ọjọ kẹjọ, oṣu kẹjọ, ni wọn yoo tẹ oku ni itẹ ẹyẹ. Aago mọkanla aarọ si marun-un irọlẹ ni titẹ oloogbe nitẹ ẹyẹ yoo waye, ti awọn eeyan yoo maa wo o.

Ọjọ kẹsan-an gan-an ni wọn yoo sin Pasitọ T.B Joshua, aago mẹwaa aarọ ni eto isinku yii yoo bẹrẹ.

To ba di lọjọ kọkanla ni isin idupẹ yoo waye, aago mẹsan-an aarọ si mọkanla ni wọn yoo fi ṣe e.

  Wọn ko ṣai fi i kun un pe ilu Eko ni gbogbo eto isinku yii yoo ti waye, bẹẹ ni Eko yii naa ni wọn yoo sin pasitọ agba naa si pẹlu.

Gbogbo bi eto isinku kọọkan ba ṣe n lọ ni wọn yoo maa ṣafihan rẹ lori tẹlifiṣan Emmanuel ti i ṣe ti oloogbe naa, bẹẹ naa ni yoo si maa han lori awọn ẹka ayelujara.

Ọjọ karun-un, oṣu kẹfa, ni Pasitọ T.B Joshua dagbere faye, ẹni ọdun mẹtadinlọgọta ni i ṣe.

Leave a Reply