Oju oorun ni Dauda ti dide, o si ja bọ latori ile alaja mẹta n’Ilọrin, lo ba ku patapata 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Oorun ni gende-kunrin ẹni ọgbọn ọdun kan, Ọgbẹni Dauda, lọọ sun lori ile alaja mẹta kan to wa ni agboole Oniyọ, Ita-Mẹrin, Ilọrin, ipinlẹ Kwara, to fi ja bọ to si gba ibẹ ku.

Iroyin to tẹ ALAROYE lọwọ lọjọ Aje, Mọnde, ọṣẹ yii, ni pe lalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọṣẹ to kọja, ni Dauda gun oke alaja mẹta to wa ni agboole wọn lọ lati lọọ sun latari ooru to mu, sugbọn ni nnkan bii aago mejila oru mọju ọjọ Abamẹta, lo dide nilẹ lati oju oorun bọya o n ṣe iranran ni o, ko sẹni tọrọ ọrọ naa ye, o ja bọ lati ori ile ọhun. Bo tilẹ jẹ pe awọn mọlẹbi gbinyanju, wọn gbe e lọ sileewosan, ṣugbọn ẹpa ko boro mọ, ẹlẹkọ ọrun ti polowo fun un, o si ti ra a.

Dauda ni wọn sọ pe o sẹṣẹ gbominira nibi iṣẹ eroja ara ọkọ tita to kọ ni Ipata-Ọlọjẹẹ, ko too di pe o ku loru mọju ọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ to kọja yii, wọn si ti sin in nilana ti Musulumi.

Leave a Reply